Ogún Naira ni mo gbà fún Sinímá Ọ̀pá Ajé tó sọ mí di olókìkí – Àjan Abija
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọ̀kan gbòógì òṣèré sinimá àgbéléwò ayé àtijọ́, Alhaji Adeyẹmi Sikiru tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí “Ajan Abija” ti ké gbàjarè lórí àwọn ìpèníjà tó ń bá a fínra lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí ó ti fi ojú hàn nínú àwọn sinimá àgbéléwò tó kálé-kákò.
Ninu ọrọ ti o ba sọ, Sikiru ni oun ko mọ wi pe dandan ni ki olokiki ni owo lọwọ tabi ki o ko ọrọ jọ lasiko ti oun n bẹ lẹnu iṣẹ tiata.
Ọkan lara awọn ere to sọ Alhaji Sikiru di olokiki nigba naa lọhun ni sinima kan ti wọn pe ni Ọpa Aje ninu eleyii ti o ti kopa gẹgẹ bii Ajan Abija
Alaye to ṣe fun akoroyin wa ni pe ogun Naira pere ni oun gba lori sinima naa, nitori ilepa owo tabi ọrọ ko si ni ọkan oun ni gbogb asiko yii.
Wọn maa n saba kun arakunrin yii ni ẹfun ninu awọn ipa to ko ninu sinima, eyii lo si faa to fi nira fun ọpọlọpọ eeyan lati daa mọ.
O fi kun ọrọ rẹ wi pe inu ipenija nla ni oun wa bayii, nitori pe awọn iṣẹ idọti ni oun n ṣe bayii nitori atijẹ, bẹẹ sini alaafia ara oun tun ti di fiafia.