Ogún Mohbad wà lára n tó n dìjà sílẹ̀ láàrin ẹbí méjèèjì- Iyabo Ojo
Fẹ́mi Akínṣọlá
Yorùbán ní bí
ọ̀rọ̀ ńlá kò bá tí í tán, èèyàn ńlá kò ní-ín sinmi àròyé.
Gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin onítíátà ilẹ̀ wa nnì, Iyabo Ojo, ti tún ṣí aṣọ lójú eégún lórí ọ̀rọ̀ ìjà ojoojúmọ́ tó ń lọ láàrin ẹbí Olóògbé Mohbad àti Wunmi tí í ṣe ìyàwó rẹ̀.
Nínú ọ̀rọ̀ tí Iyabọ Ojo sọ lórí ètò kan lórí ẹ̀rọ ayélujára lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹtádínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá, ọdún 2023 yìí, ló ti sọ pé àwọn dúkìá olóògbé ọ̀hún kọ̀ọ̀kan tó wà níkàáwọ́ ẹbí ìyàwó olóògbé náà ló n díjà sílẹ̀ láàrin àwọn ẹbí méjèèjì nígbà gbogbo.
Àìmọye ìgbà ni Alàgbà Joseph Alọba tí í ṣe bàbá olóògbé ti fẹ̀sùn kan ẹbí ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé àwọn gan-an ni kò jẹ́ kí ọmọ òun gbé ohun gidi ṣe fóun làtìgbà tí ìràwọ̀ rẹ̀ ti gòkè nídìí iṣẹ́ tó yàn láàyò.
Iyabo Ojo ní, ‘ Kì í ṣe ìròyìn mọ́ rárá pé bàbá olóògbé yìí kì í fi bò nígbà gbogbo tó bá lanfaani láti bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ pé ìyàwó ọmọ òun àtàwọn ẹbí rẹ̀ ni wọn kò jẹ́ kí ọmọ òun ṣètọ́jú òun nígbà ayé rẹ̀. Bàbá olóògbé pàápàá tiẹ̀ ti fìgbà kan pè mí rí lórí fóònù, tó sì sọ b’áwọn ẹbí ìyàwó ọmọ rẹ̀ ṣe ti gbẹ́sẹ̀ lé àwọn dúkìá ọmọ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan, mi ò fara mọ́ èyí rárá ’.
Bákan náà ló jẹ́ pé àwọn ẹ̀sun ńlá gbogbo ti bàbá olóògbé fi kan ìyàwó ọmọ rẹ̀ kò dùn mọ́ ìyàwó yìí nínú rárá, tó sì ń fojú kò tọ́ wo bàbá ọkọ rẹ̀ báyìí.