PDP ń fa Goodluck Jonathan lójú mọ́ra láti dupò ààrẹ lọ́dún 2027

Ọgbọ́n yà bí ọ̀nà,PDP ń fa Goodluck Jonathan lójú mọ́ra láti dupò ààrẹ lọ́dún 2027

Fẹ́mi Akínṣọlá

Oníkálùkù ló ń ṣe kíyọ̀ ó dun ti òun.
Ojúmó kan, àrà tuntun ló ń jáde lágbo òṣèlú lorilẹ èdè Nàìjíríà. Tuntun tó tún jáde ni ìròyìn tó ní, ẹgbẹ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, ti ń jíròrò láti fa ààrẹ orílè-èdè Nàìjíríà nígbà kan rí, Goodluck Jonathan kalẹ gẹgẹ bíi oludije fún ètò ìdìbò Ààrẹ lọdun 2027.

Jonathan lo ti gba isinmi lẹnu iṣẹ oṣelu lati igba to ti lulẹ lọdun 2015 ninu eto idibo aarẹ, ti ẹgbẹ oṣelu PDP si ti fidi rẹ mulẹ pe, ijiroro ti bẹrẹ pẹlu Jonathan lati jade dupo aarẹ tako Aarẹ Bola Tinubu ninu eto idibo to n bọ.

Awọn amoye kan gbagbọ pe igbesẹ nla ree lati dena de apapọ awọn ẹgbẹ kan.
Iroyin to tẹ wá lọwọ ni pe PDP, pẹlu ajọsepo awọn gomina ati olori labẹ ẹgbẹ oṣelu naa n gbiyanju lati ba Aarẹ Jonathan sọrọ lati jade dupo aarẹ ninu eto idibo ọdun 2027.

Malam Ibrahim Abdullahi, igbakeji agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP, fidi iroyin naa mulẹ, to si jẹ ko di mimọ pe Jonathan setan lati fọ ohun rere si ibeere ẹgbẹ oṣelu PDP.

O ni igbesẹ lati fun Jonathan ni asia ẹgbẹ naa lo da lori ibeere awọn ọmọ Naijiria lati gbe aarẹ nigba kan ri naa pada nitori awọn araalu ti ri pe awọn se asise nla nigba ti wọn dibo tako Jonathan lọdun 2015.
“Niwọn igba to si wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, a si le wa sita. Nigba ti awọn araalu ti mọ pe ohun to waye tẹlẹ ki n ṣe ẹjọ rẹ, wọn fun ni suuru, ti wọn si n bẹ Ọlọrun pe ko ran eeyan gidi wa .”

“Nigba ti a si nifẹ araalu lọkan, ti a si fẹ nnkan to da fun wọn, a ri pe o ṣe koko lati tẹ eti si ibeere araalu, ka si wa ọna abayọ si, ” Malam Ibrahim Abdullahi ṣalaye.

Bakan naa ni BBC tun gbọ pe ọpọ awọn olori ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, tẹle Jonathan lọ si orilẹede Gambia ni ọsẹ to kọja pẹlu erongba lati ba sọrọ pe ko wa dije dupo aarẹ.

Lọwọ yii, Malam Ibrahim Abdullahi, ni aarẹ nigba kan ri ọhun n fi ami han pe yoo tẹwọgba ipe lati ọwọ PDP, to si tun ti fi awọn ohun to le di lọna silẹ.

O ni, “o ti n ba awọn eeyan sọrọ, to si n fun wọn ni ohun to le mu u dije fun ipo aarẹ.”

Onimọ nipa oṣelu, Ọjọgbọn Abubakar Kari ti fasiti ilu Abuja, gbagbọ pe eyi yoo fa ọpọ kudiẹkudiẹ ninu eto idibo ọdun 2027.

O ni, “ti Goodluck ba dije, ategun tuntun yoo de ba PDP, eyi ti wọn nilo tipẹ. Mo gbagbọ pe ijade Goodluck Jonathan yoo mu ifasẹyin ba awọn ẹgbẹ oṣelu to korajọ nitori awọn ni igbagbọ wa pe wọn yoo jẹ alatako nla.”

Ẹwẹ, iroyin mii tun jade pe PDP n ba gomina tẹlẹ nipinlẹ Kano, Sẹnetọ Rabiu Musa Kwankawso, sọrọ lati jade dupo gẹgẹ bi igbakeji pẹlu Goodluck Jonathan.