Òfin tó de gíláàsì mọ́tò dúdú di àfìsẹ́yìn
Ìròyìn òwúrọ̀
Lati ọdun to kọja ni ajọ awọn ọlọpaa ti salaye pe awọn maa fi ọwọ sinkun ofin mu mọto to ba lo gilaasi dudu.
Eyi mu ki ajọ awọn Agbẹjọro GBA ile ẹjọ lọ. Wọn ni inira wa ni ilu tẹlẹ, awọn mọto yii naa wa pẹlu gilaasi dudu ni, owo ti ajọ ọlọpaa tun fe maa gba jẹ owo ọdọọdun.
Gbogbo eyi ni ajọ Agbẹjọro gbe lọ si ile ẹjọ, wọn si jare bọ. Ile-ẹjọ ni ọlọpaa kankan ko gbọdọ da mọto kankan duro nitori gilaasi dudu.
Ti ko ba si ti idajọ naa ni December 17, 2025, pẹlu nọmba HOR/FHR/M/31/2025, oni ọjọ keji osu kejila ni awọn ọlọpaa ko ba ti bẹrẹ si ni fi ọwọ sinkun ofin mu mọto.
Gẹgẹ bi alukoro awọn ọlọpaa, Benjamin Hundeyin se salaye fun oniroyin ni ọjọ kin-in-ni osu yii pe awọn ko gbọdọ kọ eti ikun si idajọ ile ẹjọ.
O ni igbẹjọ miiran tun maa waye ni ogunjọ osu yii ni eyi to maa jẹ ki awọn mo odo ti awọn maa da ọrunla si.









