Òfin tó bá mú ẹrú yẹ kó mú ọmọ – Obi
Yínká Àlàbí
Adije du ipo Aarẹ lọdun 2023, alagba Peter Obi lo n salaye yii loju opo X rẹ lọjọ isẹgun ọjọ kejila, osu kẹjọ ọdun yii. O ni ohun ti ajọ AON (Airline Operators of Nigeria) ati Ibom Air se lori arabinrin Comfort Emmanson fun iwa ti ko dara to wu ninu baluu naa. Awọn ajọ yii ni ko gbọdọ wọ baluu mọ laye rẹ bẹẹ ni ile ẹjọ tun ju u si atimọle ni Kirikiri ni oju ẹsẹ.
Obi nI awọn to sẹ ẹsẹ to ju ti obinrin yii lọ si n rin, wọn n yan fanda ni ilu. O ni idajọ yii ku diẹ kaa to, “ofin wa ko gbọdọ maa mu ẹru ko ma mu ọmọ nitori bi a se bi ẹru naa ni a bi ọmọ”.
Ogbeni Achimugu to jẹ ọga Nigerian Civil Aviation Authorithy Director of Public Affairs and Consumer Protection naa ni idajọ naa ku diẹ kaa to, o ni o yẹ ki awọn si le gbe iru ẹjọ bẹẹ kuro ni ile ẹjọ ki awọn si fun Comfort ni ijiya miiran.
Obi ni iru idajọ ologun bẹẹ ko yẹ iru arabinrin naa., ki ọdọmọbinrin to wa ni aarin ogun ọdun rẹ ma le wọ ọkọ ofurufu mọ laye rẹ. O ni o yẹ ki ijọba wa nnkan se sii.