Odun mewaa ni mo lo ni primary school – Ajobiewe

Ajobiewe

Odun mewaa ni mo lo ni primary school – Ajobiewe

Bayii ti gbajugbaja apesa egungun, Sulaiman Ajobiewe Aremu, pe eni addome odun – 70 years- like eepe, a ko le sai maa ranti awon nnkan nla  ti Olorun ti se laye re o.

Ajobiewe lo ye ki a maa ko orin o dun, o po, o pe, fun, tori, gege bi Sunny Ade se ko o, Oluwa lo n fun ni.

Lati nnkan bii ogoji odun ni Ajobiewe ti di ilumomika akewi ibile, to si je pe okiki re tubo n gbooro sii ni.

Bi o se n te awon ara ilu lorun, bee naa ni toba-tijoye n sugbaa re.

Sugbon sa o, oro Ajobiewe, akuko ti yoo ko ni, asa ko ni gbe e.

Bee, eni ti yoo ga, ese re a tin-in-rin.

Nigba to wa ni kekere, bo tile je pe kadara re maa so o di igilango pesa eegun, opolo re ko ji si iwe rara.

Funra Ajobiewe lo fenu ara re so eleyii, gage bi IROYIN OWURO se ranti, ninu iforowero kan to se pelu iwe iroyin THE PUNCH, ni odun die seyin.

Latari eleyii, odun mewaa gbako lo lo ni ile eko alakobere, nibi to ye ko ti lo mefa.

Leyin eleyii lo lo ko ise buredi sise, sugbon to je pe ife to ni si esa pipe je ki o se opo iwadii ijinle, eyi to ran an lowo lati di ilumomika lonii.

Nje e tile wa tun t gbo?

Musulumi ni Ajobiewe, eni to je omo bibi Ila Orangun.

Kii muti, ki mu siga, bee ni kii se oogun isoye.

Pabambari ibe ni pe bo se je gbajugbaja to, iyawo kan soso lo ni.

Ko to feyawo naa nko? O ti to omo gbon odun tori arinka to maa n ja bata!

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here