Ọdún Àjíǹde: AIG Jimoh fọwọ́ gbáyà ètò ààbò ní Eko àti Ogun
Igbakeji ọga patapata ọlọpaa ni orileede yii AIG Olohunde Jimoh ti Zone 2 labẹ ipinlẹ Eko ati Ogun ti rọ awọn araalu lati fi aaye gba ifẹ ki alaafia le jọba ninu aye wa, paapaa julọ ni asiko ti awọn ọmọ lẹyin Jesu kirisiti n s’ọdun Ajinde yii.
AIG jimoh salaye yii nigba to n pe DSP Afolayan Gbenga l’ọjọ Abameta ni Eko, asiko yii lo n salaye gbogbo eto aabo to wa nilẹ fun ọdun naa.
AIG salaye ọdun Ajinde Jesu gẹgẹ bi ọdun pataki to sọ bi Olugbala se ji dide to jawe olubori lori iku, ẹsẹ ati aisan ki eniyan le baa wọ ijọba Ọlọrun.
O salaye bi ọdun naa se salaye bi imọlẹ se jọba lori okunkun, to si fun wa ni ọjọ iwaju rere to tun sọ wa di atunbi.
AIG gba gbogbo olugbe ipinlẹ Eko ati Ogun nimọran pe ki a jẹ ki alaafia, ifẹ ati ifarada jọba ninu ọkan wa ki a le gbe igbe aye rere.
Ọga ọlọpaa yii salaye gbogbo akitiyan ijọba lati le jẹ ki alaafia jọba nipa kiko awọn ọlọpaa kaakiri awọn ile ijọsin ati lati jẹ ki awọn mọto ọlọpaa kan maa kaakiri gbogbo awọn ile igbafẹ ti awọn eniyan ti le fẹ naju lasiko ọdun yii.
AIG gba awọn aralu nimọran pe ki wọn tete kan si agọ ọlọpaa to ba wa nitosi wọn ti wọn ba kẹfin nnkankan tabi iwa idunkooko mọ ni lagbegbe wọn.









