Obìnrin tó bá dálémosú kò lè tó̩jú o̩mo̩kùnrin – Jim Iyke

Obìnrin tó bá dálémosú kò lè tó̩jú o̩mo̩kùnrin – Jim Iyke

Mary Fágbohùn

Osere tiata, Jim Iyke ti so pe obinrin to dalemosu tabi to n danikan gbe bukata ko le to omokunrin dagba bii “okunrin to ni laari.”

Nigba to n soro ninu iforowero kan ni ileese redio Okay 101.7 FM, Accra, Ghana, Iyke so pe obinrin nilo iranlowo iduro okunrin lati le to okunrin to ni laari.

O ni awon obinrin ni a seda lati toju ki won si nifee, sugbon won le ma ni agbara ibaniwi ati itoni ti okunrin nilo.

O ni, “Obinrin ko le to okunrin dagba. O ko le se e, bee ko la se da o. Obinrin to dalemosu ko le to okunrin to ni laari. O nilo iduro okunrin kan – lo wa arakunrin re to n se daadaa tabi baba re tabi okunrin kan to le gbekele. Okunrin kan gbodo wa nibe [lati to omokunrin dagba].

“Nitori a seda obinrin lati toju, lati nifee. Nigba ti o ba wa fe danikan se, wa to okunrin ti ko laapon dagba ni? Yoo dabi okunrin to fi o sile. O nilo enikan lati baa wi, lati so fun un pe ‘Rara’ ni gbogbo igba to ba seese, lati le je ki ese re mule,” o safihan.

Amo sa, oro re yi mu ikunsinu jade, pelu bi awon kan se jiyan pe obinrin to dalemosu pe lati toju omo dagba ni gbogbo ona, awon omo ti ko ni woju enikan lati je.

Gege bi won se so, pelu atileyin ti o to ati sise obi, obinrin to dalemosu ko le to omokunrin re lagbara pelu ebun ati ohun to nilo lati ni igboya ninu ara re, ko le se ise okunrin elegbe re.