‘Obìnrin ló wa ọkọ̀ ‘one chance’ tí mo wọ̀, wọ́n lù mí bíi kí n kú, wọ́n tún fi aboniki sí mi lójú’
Fẹ́mi Akínṣọlá
Nígbà tí Korede Ogunseinde, ẹni ọgbọ̀n ọdún, ń jáde kúrò nínú ilé rẹ̀ lọ́jọ́ kejì, oṣù Kẹfà, ọdún 2025, gbogbo ìrètí rẹ̀ ni láti mórílé ibiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀.
Ọkùnrin náà, onímọ̀ ẹ̀rọ jáde síta láti lọ wọkọ̀ lọ sí ibiṣẹ́ rẹ̀ tọ wà ní agbègbè Victoria Island, ìpínlẹ̀ Eko.
Ní ibùdókọ̀ tó wà ló ti rí ọkọ̀ kan tó ń wá èrò lọ sí Obalende tó sì wọ ọkọ̀ náà.
Ó ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun nígbà tí òun ri pé, obìnrin ni awakọ̀ èrò náà tí òun sì ń rò ó pé obìnrin kan ló ń gbìyànjú láti wá oúnjẹ oòjọ́ rẹ̀.
“Inú mi dùn láti rí obìnrin nídìí iṣẹ́ tó jẹ́ pé àwọn ọkùnrin ló sábà máa ń ṣe é. Mo kan sáárá sí i fún iṣẹ́ tó ń ṣe láì mọ̀ pé iṣẹ́ burúkú ló ń ṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀.”
Ó ṣàlàyé pé nígbà tí òun fẹ́ wọkọ̀ ọ̀hún, òun bá àwọn obìnrin méjì tí wọ́n ti wà nínú ọkọ̀ náà, táwọn ọkùnrin méjì míì sì darapọ̀ mọ́ àwọn káwọn tó kúrò ní ibùdókọ̀.
“Bí a ṣe ń lọ ni mò ń gbọ́ tó dàbí pé obìnrin tó wà lẹ́yìn mi ń sunkún, tó ń bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n má pa òun.
“Lẹ́yìn náà ni ọkùnrin tó wà ní ẹ̀gbẹ́ mi bẹ̀rẹ̀ sí ní nà mí, ìgbà yẹn ló ye mí pé a ti wọkọ̀ àwọn alọ́nilọ́wọ́ gbà.”
Korede ní láti ìgbà tí òun ti máa ń gbọ́ pé àwọn èèyàn wọkọ̀ àwọn alọ́nilọ́wọ́ gbà, tí wọ́n máa ń pè ní “one chance”, òun máa ń rò ó pé àwọn èèyàn náà kò mọ ara á ṣọ́ tó ni àyàfi ìgbà tó ṣẹlẹ̀ sí òun náà báyìí.
Ó ní ọkùnrin náà lu òun gidigidi pàápàá ní orúnkún èyí tó mú ìnira gidi bá òun, tó sì jẹ́ pé níṣe lọ dàbí pé wọ́n ń gún obìnrin tó wà lẹ́yìn òun lọ́bẹ ni.
“Bí wọ́n ṣe ń gun ni mò ń gbọ́ pé ara rẹ̀ ń ya.”
Ó fi kun pé nígbà tó yà ni wọ́n dúró tó sì dàbí pé wọ́n lọ fi káàdì ATM obìnrin náà gba owó lẹ́nu POS tí wọ́n sì ń dunnú pé àwọn rí owó gidi gbà lọ́wọ́ obìnrin náà.
Ó ní àwọn tún tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò àwọn táwọn èèyàn náà sì fi ohun tó jọ rọ́ọ̀bù tàbí àbóníkí ra òun lójú kí wọ́n tó ti òun bọ́ sílẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀.
Ẹlòmíràn tó tún sọ̀rọ̀ ni Victoria Akpan tí òun náà ti kó sọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ láabi yìí rí.
Victoria ṣàlàyé pé níṣe láwọn èèyàn náà la irin mọ́ òun lójú, ẹsẹ̀ àti gbogbo ara tí wọ́n sì ń bèèrè káàdì ATM lọ́wọ́ òun tó sì jẹ́ pé òun kò ní.
“Ní ọdún 2021 ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé tó sì jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ mi ní ìpínlẹ̀ Eko.
“Wọ́n lù mí, fúnmi lọ́rùn débii pé itọ́ funfun ń jáde lẹ́nu mi kí wọ́n tó fi mí sílẹ̀.”
Korede gbàgbọ́ pé àwọn oníṣẹ́ ibi yìí tún ti ń pọ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko àti pé ìjọba nílò láti tètè mójútó wọn ní kíákíá nítorí ọṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe kò kéré.
Ọ̀pọ̀ àwọn tó máa ń ṣe irú iṣẹ́ láabi yìí ló máa ń lo ọkọ̀ aládani láti fi gbé àwọn èrò ní ibùdókọ̀, tí wọ́n sì máa ń tó mẹ́ta sí mẹ́rin tí wọ́n jọ máa ń ṣiṣẹ́ papọ̀.
Fún Ahmed Morufu, ó ní ọ̀pọ̀ àwọn oníjìbìtì máa ń rí iṣẹ́ wọn ṣe nítorí ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà ṣe é.
Ó ní lọ́pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń dín owó ọkọ̀ wọn kù sí iye tó jẹ́ kí àwọn le wọ̀ wọ́n ní kíákíá.
Ó sọ pé èèyàn ti máa wọ̀ ọ́ tán kó tó mọ̀ pé ‘one chance’ ni òun wọ̀.
Nínú ọ̀rọ̀ tó sọ, agbẹnusọ ọlọ́pàá Eko, Benjamin Hundeyin sọ pé kò sí àkọ́ọ́lẹ̀ ẹ̀sùn “one chance” ní àgọ́ àwọn.
Ó ní èyí túmọ̀ sí pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò máa wáyé tàbí kó jẹ pé àwọn tó ń ṣẹlẹ̀ sí kò máa fẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá.
Hundeyin fi kun pé gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó mọ iṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, àwọn ti kò àwọn ikọ̀ ọlọ́pàá tó ń gbógun ti ìwà ọ̀daràn lọ sáwọn agbègbè tí irúfẹ́ ìwà báyìí ti le máa wáyé.
Ó ní ìgbésẹ̀ àwọn yìí ti ń mú àdínkù bá ìwà ọ̀daràn ní ìpínlẹ̀ Eko.