Obasanjo fẹ́ dupò ààrẹ Nàìjíríà fún sáà kẹ́ta. Ààrẹ tẹ́lẹ̀ sàlàyé

Obasanjo fẹ́ dupò ààrẹ Nàìjíríà fún sáà kẹ́ta. Ààrẹ tẹ́lẹ̀ sàlàyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà sọ pé bí ọ̀rọ̀ ńlá kò bá tí ì tán, èèyàn ńlá kò ní-ín sinmi àròyé .

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹlẹri, Olóyè Olusegun Obasanjo ti sàlàyé pé irọ́ gbuu tó jìnà sí òótọ́ lọ̀rọ̀ t’áwọn èèyàn kan ti n gbé pòòyì ẹnu pé òun gbìyànjú láti dupò Ààrẹ fún sáà kẹta.

Obasanjo fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ níbi ìjíròrò lórí ètò ìjọba àwarawa tí Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí, Goodluck Jonathan, ṣagbàtẹrù rẹ̀ nílùú Accra, tí í ṣe olu ìlú orílẹ̀-èdè Ghana.

Obasanjo ni ko si ẹni to ni ẹri to le fidi rẹ mulẹ pe loootọ loun gbiyanju lati dupo aarẹ Naijiria fun saa kẹta lẹyìn toun lo saa meji tan.
“Kìí ṣe pe ori mi o pe. Mo mọ nnkan ti mo le ṣe ti mo ba fẹ dupo aarẹ fun saa kẹta.

Ko si ọmọ Naijiria kan yala eyi to ti ku tabi wa laaye to le sọ pe mo pe oun wi pe mo fẹ dupo aarẹ fun saa kẹta,” Obasanjo lo sọ bẹẹ.
Aarẹ ana naa fikun ọrọ rẹ pe biba awọn ti Naijiria jẹ lowo sọrọ lati fagile gbese ti Naijiria jẹ le ju ki oun gbiyanju lati dupo aarẹ fun kẹta lọ.

Obasanjo ni “gbogbo igba ni mo maa n sọ ọ pe ti mo ba fẹ dupo aarẹ fun igba kẹta ni toootọ ni, n ko ba ṣe bẹẹ, torí o rọrun fun mi lati lọ fun saa kẹta ju riri idarijin gba fun gbese ti Naijiria jẹ lọ.”
Aarẹ Naijiria tẹlẹ wa kìlọ fawọn olori orilẹede ti wọn kii fẹ fipo silẹ lati jawọ lapọn ti ko yọ.

Obasanjo ni lasiko ti eeyan ba si wa ni abarapa ni eeyan maa lokun lati le ṣiṣẹ daadaa.

“Ti ara ba ti di kujẹ kujẹ, eeyan o ni le ṣe ọpọ nnkan daadaa mọ.

Amọ, mo mọ pe awọn kan maa n ro wi pe t’awọn ko ba si níbẹ, ko si ẹlòmíràn to le ṣe e.

Wọn tiẹ tun máa n sọ pe awọn o tii ri ẹlomiran, mo ni igbagbọ pe ẹṣẹ ni eyi jẹ si Ọlọrun.

Idi ni pe Ọlọrun le gba ẹmi rẹ nigba kugba ti ẹlomiran yóò si bọ si ipo rẹ.

Ẹni to ba si bọ sí ipo rẹ naa le ṣe daadaa ju ọ lọ, o si tun le ma ṣe daadaa to ọ,” Obasanjo ṣalaye.