Ọba Ṣoun Ogbomosho ń forígbárí pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọbíbí ìlú
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà sọ pé bí ọ̀rọ̀ ńlá kò bá tí ì tán èèyàn ńlá kò ní-ín sinmi àròyé rárá, bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú bí
awuyewuye mìíràn tún ti ṣẹ́yọ nílùú Ogbomọṣọ lẹ́yìn táwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ aláṣẹ Ogbomoso Parapọ̀ Àgbáyé tí Soun ìlú Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye Orumogege Kẹta, ti túká ké gbà jarè e pé kábíyèsí náà kò lágbára láti tú ìgbìmọ̀ náà ká.
Ninu fọnran kan ti alukoro ẹgbẹ naa, Kọmureedi T.M. Balogun, alaga abẹle ẹgbẹ naa, Alhaji Iliasu Jamiu ati ati akọwe abẹle, Arabinrin Janet Akintoyinbo fi ranṣẹ sawọn ileeṣẹ iroyin ni wọn ti ṣalaye pe igbesẹ Ọba Olaoye tako iwe ofin ati ilana ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye.
Awọn oloye ẹgbẹ naa ko ṣai fidi rẹ mulẹ wi pe awọn ko tabuku tabi ṣe arifin si kabiyesi, ṣugbọn awọn n tẹle nnkan to wa ninu ofin ẹgbẹ naa ni.
Awuyewuye mii tun ti ṣẹyọ niluu Ogbomoso lẹyin tawọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ alaṣẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye ti Soun ilu Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye Orumogege Kẹta, ti tuka ke gbajare wi pe kabiesi naa ko lagbara lati tu igbimọ naa ka.
Ninu fọnran kan ti alukoro ẹgbẹ naa, Kọmureedi T.M. Balogun, alaga abẹle ẹgbẹ naa, Alhaji Iliasu Jamiu ati ati akọwe abẹle, Arabinrin Janet Akintoyinbo fi ranṣẹ sawọn ileeṣẹ iroyin ni wọn ti ṣalaye pe igbesẹ Ọba Olaoye tako iwe ofin ati ilana ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye.
Awọn oloye ẹgbẹ naa ko ṣai fidi rẹ mulẹ wi pe awọn ko tabuku tabi ṣe arifin si kabiyesi, ṣugbọn awọn n tẹle nnkan to wa ninu ofin ẹgbẹ naa ni.
Lọsẹ to kọja ni Kabiyesi Ọba Ghandi Olaoye to jẹ baba isalẹ ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye kede pe oun ti tu igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa ka.
Kabiyesi si gbe igbimọ fidihẹ kan dide eyi ti Ọjọgbọn Olusegun Ajiboye to jẹ akọwe agba ẹgbẹ to n ri si iforukọsilẹ awọn olukọọ, TRCN, tẹlẹ jẹ adari rẹ.
Igbimọ yii ni ori ade naa sọ pe yoo maa ṣakoso ẹgbẹ naa lọwọ yii.
Ọba Olaoye ni oun tu igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa ka fun atunto ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye ki ẹgbẹ naa le wa ni ibamu pẹlu eto idagbasoke ọlọdun mẹẹdọgbọn oun fun ilu Ogbomoso.
Amọ, ọpọ lo ti n sọ pe igbesẹ kabiyesi ko ṣẹyin ibaṣepọ ori ade naa ti ko dan mọran pẹlu awọn oloye ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye, eyi to jẹ ki ọpọ ninu wọn jinna si aafin.
Iroyin kan tiẹ fidi rẹ mulẹ wi pe aarẹ ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye tẹlẹ to doloogbe loṣu Kẹfa ọdun yii, Adajọ fẹyinti Afolabi Adeniran, kuna lati wa ojutuu si faakaja to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa.
Iroyin naa sọ pe eyi gan an lo jẹ ki kabiyesi gbe igbesẹ to gbe tori o dabi ẹni pe awọn kan ti fẹ ja ẹgbẹ Ogbomoso Parapo Agbaaye gba.