Ó ye̩ kí n ti fè̩yìntì nínú isé̩ orin’ – Rudeboy
Mary Fágbohùn
Olorin, Paul Okoye, ti a mo si Rudeboy, ti so pe oun ati awon akegbe re ni o ye ki won ti feyinti ninu ise orin bayii.
Eni Odun marundinlaadota naa so pe ninu ilana orin, ko ye ki olorin sise fun igba ti o pe.
Nigba to n soro lori eto Adesope, Rudeboy ni, o je nnkan ti o soro fun okunrin ti o ni idile lati je olorin ti o n sise gidi.
“Ni ilana ti a fi n ko orin tele, awon bii tiwa bayii ye ki o ti feyinti,” gege bi o se salaye.
“Gbogbo nnkan ni akoko wa fun ni aye yi. Awon nnkan a maa sele. Ti o ba je Ilumooka ti o si ro pe gbogbo igba ni awon eniyan yoo maa ri o bii Angeli, gba mi gbo, ko si ibi ti o n lo. Igba kan wa ti awon nnkan ko ni ba o lara mu. Bee lo se maa n ri.
“Gbogbo awon gbajumo olorin ni won ti ni idalebi tabi awuyewuye ri. Koda, awon ti won se n dide bo, pelu, yoo ni ipin ninu re lojo kan. Bii nnkan se ri ni [ninu ile ise alarinrin]. Sugbon, ohun ti o niise ju ni iru eni ti o je ati bi o ba se koju re.”
Rudeboy di olokiki ni 2000 bii okan lara awon olorin P-Square pelu Ikeji re Peter Okoye, ti a mo si Mr P.
Awon egbe naa ni o koko pinya ni 2016 sugbon ti won pada re ni 2021. Ni osu kejo 2024, Rudeboy fi idi re mule pe P-Square tun ti pinya, leyin ti arakunrin re Peter fi esun kan oun ati egbon won, ti o je alakoso won teleri, Jude Okoye pe won fi owo egbe naa si apo ara won.