Ó mà s̩e o! Liverpool àti Portugal pàdánù ako̩ni

Ó mà s̩e o! Liverpool àti Portugal pàdánù ako̩ni

Yínká Àlàbí

Ibanuje̩ wo̩le to̩ e̩gbe̩ agbabo̩o̩lu liverpool ati orileede Portugal ni idaji oni, nigba ti ijamba mo̩to se̩le̩ si Diogo Jota. Ogunna gbongbo ni Diogo je̩ ninu iko̩ agbabo̩o̩lu Liverpool be̩e̩ naa ni orileede Portugal ko le koyan re̩ ki wo̩n ma fewe boo to ba ti je̩ ibi boolu gbigba. Aimo̩ye ife e̩ye̩ lo wa lo̩wo̩ re̩ nibi to dara de. O ma s̩e o! Iku bo̩la je̩.
PFF (Portuguese Football Federation) lo fi iroyin naa lede laipe̩. Diogo ati aburo re̩ André Silva ni wo̩n jo̩ wa ninu mo̩to ayo̩ke̩le naa. Ijamba mo̩to naa waye ni Cernadilla, Zamora ni northwestern ti Spain, o si da e̩mi awo̩n mejeeji legbodo.
Diogo se igbeyawo pe̩lu Rute Cardoso ni o̩s̩e̩ meji seyin, bi o tile je pe won ti bimo meta funra wo̩n.
O̩mo̩ o̩dun mejidinlo̩gbo̩n (28 years) ni Diogo nigba ti Andre je̩ o̩mo̩ o̩dun me̩rindinlo̩gbo̩n (26 years). Iko̩ agbabo̩o̩lu Penafiel ti ipele keji ni orileede Portugal lo n gba bo̩o̩lu fun.
Gbogbo iko̩ agbabo̩o̩lu Liverpool ati Portugal ku ase̩nde.