Ó kàsíàrà , wọ́n ká òògùn olóró mọ́ òṣìṣẹ́ NDLEA lọ́wọ́

Ó kàsíàrà , wọ́n ká òògùn olóró mọ́ òṣìṣẹ́ NDLEA lọ́wọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kólékólé dasọ́de,jàgùdà di baálẹ̀ ọjà.Òbìlẹ̀jẹ́ ò kọ̀ kí n kan ó bàjẹ́.
Ọwọ́ ikọ̀ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ti ba ọkùnrin agbóògùn olóró kan, Kelechi Chukwumeeije, tó pe ara rẹ̀ ní òṣìṣẹ́ àjọ tó ń rí sí ìlòkulò oògùn olóró nílẹ̀ wa, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA) lọjọ Àìkú, ọjọ́ kẹtala, oṣù Kẹjọ, ọdún 2023 yìí, lágbègbè Cement, ní ìpínlẹ̀ Èkó, pẹ̀lú irúfẹ́ òògùn olóró kan tí wọ́n ń pè ní Marsh-Mallow, tó jẹ́ ìwọ̀n kílò mẹ́rin (4kg).

Lásìkò tí ọgá ọlọ́pàá kan, ASP Samuel Sunday, ko ikọ ọlọ́pàá sòdí láti ṣe pàtìrólùù gbogbo agbègbè náà lọ́wọ́ ba afurasí yìí ní ibùdókọ̀ tó ti fẹ́ wọkọ̀.

Nígbà ti wọ́n fi ọ̀rọ̀ pò ó nífun pọ̀ ló jẹ́wọ́ pé ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Abia lòun, àti pé òṣìṣẹ́ àjọ NDLEA, ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ náà lòun, First gate,Tin-Can Island, ló ní wọ́n pín òun sí.

Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òògùn olóró Marsh-Mallow tí wọ́n bá lára rẹ̀ ọ̀hún jẹ́ ti ọ̀ga oun kan lati ẹka àwọn tí wọ́n n pé ní Odogwu. Ló gbé e fóun, tó sì ní kí òun lọ̀ ọ́ mọ bó ṣe máa jẹ́ títà.

Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó, Benjamin Hundeyin, tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, ó ní lóòótọ́ ni ọwọ́ ba Kelechi Chukwumeeije, tó pera rẹ̀ lóṣìṣẹ àjọ NDLEA, ṣùgbọ́n ìwádìí ti ń tẹ̀síwájú lórí rẹ̀ láti lè fìdí ẹ múlẹ̀ pé ṣé lóòótọ́ lọ jẹ́ ojúlówó òṣìṣẹ̀ àjọ náà, káwọn sì fà á lé àwọn ọ̀gá wọn lọ́wọ́.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here