Ó gbẹnután, ọba alayé méjì nílùú Kwárà di olùjẹ́jọ́ ní Kóòtù lórí ìjà ilẹ̀.

Ó gbẹnután, ọba alayé méjì nílùú Kwárà di olùjẹ́jọ́ ní Kóòtù lórí ìjà ilẹ̀.

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Imí ẹran nídìí èèyàn,ọ̀rọ̀ rúnrùn,ó ti wá di sísín fiìmù bí àṣà àwọn olóyìnbó tí kò ṣeé wò tán bí awuyewuye ìjà ilẹ̀ ṣe ń lọ lọ́wọ́ nílé-ẹjọ́ Májísírèètì kan nílùú Ìlọrin, láàrin Ẹlẹjù, tìlú Ẹ́jù, Ọba Mathew Idowu Ajíbóyè, àti Ọlọ́bà ti Ìsàlẹ-Ọ̀bà, Ọba Àlàájì Maroof Afọ́láyan Adébáyọ̀, bí fọ́nrán fídíò ṣe ṣàfihàn bí àwọn olùpẹ̀jọ́, Ọba Ajiboye, ṣe rán àwọn jàndùkú kí wọ́n máa lu Ọlọ́bà, tí wọ́n sì ń yẹ̀yẹ́ rẹ̀ lásìkò tí adájọ́ ní òun fẹ́ wo fọ́nrán fídíò ọ̀hún.

Nínú fọ́nrán fídíò náà ni àwọn janduku ti lọọ ká Ọlọ́bà àtawọn alátílẹ́yìn rẹ̀ mọ́lé, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo, wọ́n ń lù í, lórí ẹ̀sùn pé òun ló wà nídìí rògbòdìyàn tó ń wáyé nínú ìlú.

Nínú ìlú Ẹ̀jù kan náà ni àwọn méjèèjì wà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tó yá ni àwọn Ọlọ́bà ya kúrò lára Ẹ̀jù, tí wọ́n sì ń jẹ́ Ọlọ́bà ti Ìsàlẹ-̀Ọbà, èyí tí wọ́n ní àwọn ti dá dúró, tí wọ́n sì ní ọba tiwọn.

Ohun tí ó ṣokùnfà awuyewuye ọ̀hún ni pé Ẹlẹjù tìlú Ẹ́jù, Ọba Matthew Ìdòwú Ajíbóyè, ta ilẹ̀ baba àwọn Ọlọ́ba, tó sì ní ọba òun ba lórí ohun gbogbo. Ṣùgbọ́n àwọn Ọlọ́ba yarí pé àwọn kì í ṣe ara Ẹ̀jù mọ́, ni wàhálà bá bẹ̀rẹ̀.

Ọba Ajíbóyè, wọ́ Ọlọ́bà lọ sílé-ẹjọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀rí fídíò tú àṣírí bí Ọba Ẹ̀jù ṣe ní kí wọ́n máa lu Àlàájì Maroof Afọláyan tó jẹ́ Ọlọ́bà, tí wọ́n sì fà á láṣọ ya, léyìi tí wọ́n ní ó ta ko òfin ilẹ̀ wa. Fídíò náà tún ṣe àfihàn bí wọ́n ṣe ní kí olórí ẹbí ilé Ọlọ́bà, ìyẹn Rahmọn Ọmọniyì, dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú tipátipá, tí wọ́n sì ń ṣọ̀rọ̀ burúkú sí i. Lẹyìn tí wọ́n wo fídíò ọ̀hún tán ni Onídàájọ Muhammad Adams, gba fídíò náà wọlé gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀rí, ó sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Karùn-ún, ọdún 2024 yìí.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here