Ó di ọ̀sán ọ̀la kí a tó kéde èsì ìdìbò ààrẹ – INEC

Ó di ọ̀sán ọ̀la kí a tó kéde èsì ìdìbò ààrẹ – INEC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Alága àjọ INEC ní Nàìjíríà, Mahmood Yakubu ti kéde pé ó di ọ̀sán ọjọ́ ìsinmi, Ọjọ́ Kẹrindinlọgbọn, Oṣù Kejì, ọdún 2023 kí àjọ náà tó bẹrẹ sí ní kéde èsì ìdìbò sípò ààrẹ àti ìdìbò sípò aṣojú ṣòfin ní Nàìjíríà.

Yakubu ló kéde rẹ̀ lásìkò tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró nínú ìdìbò tó ń lọ lọ́wọ́ náà.

Ó ní ìgbàgbọ́ àwọn nipé kí ó tó di ọ̀sán ọ̀la , gbogbo èsì yóò ti máa wọlé sí ibi ìkéde èsì ìdìbò ní Abuja.
Alága àjọ INEC ní àsìkò náà ni àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní kéde èsì ìdìbò ọ̀hún .

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here