O̩mo̩lé BBNaija, Faith bú Soso pé òun farúgbó ara tè̩lé o̩kùnrin kiri

O̩mo̩lé BBNaija, Faith bú Soso pé òun farúgbó ara tè̩lé o̩kùnrin kiri

Mary Fágbohùn

Omole BBNaija abala 10, Big Soso ti so nipa oun ati omole miiran, Faith se gbena woju ara won.

Nigba to n soro pelu Big Brother ni Ojobo, Big Soso fi esun kan Faith pe o pe oun ni agbaaya, pe oun n fi arugbo ara tele okunrin kiri ile.

Big Soso ni oun ti oro naa bi oro abuku, o ni oun gbagbo oun ni obinrin ti won bowo fun ju ninu ile.

Omole BBNaija ni idi abajo ni bi oun se gbe ara oun, o ni awon okunrin naa n ri oun bii iya, ti won si n pe oun ni “Mama Soso”, o tesiwaju lati salaye pe oun ko ba eyikeyi ninu awon okunrin naa soro nipa ibalopo ri.

O ni, “Faith n pe mi ni agbaaya, o ni mo n fi arugbo ara tele awon okunrin kaakiri, oro abuku ni eyi je fun mi nitori mo ro pe ninu ile yi mo je okan lara awon obinrin ti won bowo fun ju.

“Gbogbo won lo ri mi bii iya nitori bi mo se gbe ara mi, koda won a ma pe mi ni Mama Soso.

“Mi o ni ki won maa pe mi bee sugbon won kan bowo fun mi, won ko si nawo ibalopo si mi. Faith paapaa ti so fun mi saaju pe oun bowo fun mi, ti oun yoo si nifee sii lati je okan lara awon omo mi.”