O̩mo̩ o̩dún márùn ún ni mí nígbà tí P-Square gbé orin, ‘Bizzy Body’ jáde – Ò̩ré̩bìnrin Paul, Ifeoma
Mary Fágbohùn
Ivy Ifeoma, orebinrin olorin olugbafe eye ati enikeji P-Square, Paul Okoye, ti a mo si Rudeboy, ti safihan pe omo odun marun un ni oun nigba ti won gbe orin won ti gbogbo ile mo ni, ‘Bizzy Body” jade.
Eni odun metalelogbon naa lo si oju awe Tiktok re lati fi fonran ara re nibi to ti n jo si orin ‘Bizzy Body’ lede eyi to mu ki afenifere kan beere fun ojo ori re nigba ti orin naa jade.
Afenifere naa ko o pe: “Omo odun meloo ni oun nigba ti ololufe re ati arakunrin re gbe orin yi jade?”
Nigba ti yoo fesi, Ifeoma kan ko o pe: “Marun un.”
E ranti pe Rudeboy, eni odun mokanlelogoji, safihan Ifeoma (ti o je omo odun mejilelogun nigba naa) bii orebinrin re tuntun ni osu kejila 2022, leyin odun kan ti oun pelu iyawo re teleri Anita Okoye pinya.