O̩mo̩ mi kìí s̩e Duduke – Simi
Olórin Nàìjíríà, Simisola Kosoko, tí a mọ̀ sí Simi, ti rọ àwọn aráàlú láti jáwọ́ nínú pípe ọmọbìnrin rẹ̀, Adejare ní “Duduke.”
E ranti pe Simi gbe orin kan jade ti o pe akole rẹ ni ‘Duduke’ ni ifojusọna ibi ọmọ rẹ ni ọdun 2020.
Nitori bẹẹ, nigba ti oun ati ọkọ rẹ, akọrin ẹlẹgbẹ rẹ Adekunle Gold, ṣe itẹwọgba ọmọ wọn akọkọ ti a n pè ni Adejare ni oṣu karun-un ọdun 2020, diẹ ninu awọn ololufẹ kan bẹrẹ si ni pe ọmọbinrin wọn ni ‘Duduke’ lẹyin orin olokiki naa.
Ninu ifọrọwerọ kan laipe pẹlu VJ Adams, Simi salaye pe oun ko fe bi awọn eniyan se n pe ọmọ oun ni Duduke, o tẹnu mọọ pe ko ni itumọ.
Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, ‘Duduke’ kan jẹ́ oro asodun tí oun lò nínú orin náà láti sọ bí ọmọ rẹ̀ ṣe jẹ́ kí ọkàn òun lu pipi.
O sọ pe, “Awọn eniyan n pe ọmọbinrin mi ni Duduke, eyi ti mi o fẹran. Kii ṣe orukọ rẹ. Ko tilẹ tumọ si nnkankan. Ti o ba tumọ si nnkan ti o dara, maa gba laaye. Ṣugbọn o je bi nnkan se n lu lasan ni, duduke, duduke. Ohun ti mo tumọ si niyi. Ọkàn mi n lu bi ilu.