O̩mo̩ àlè 66 ni è̩ro̩ DNA fà jáde nínú o̩mo̩ MKO Abio̩la
Yínká Àlàbí
O̩dun kejilelo̩gbo̩n (32) ree ti ijo̩ba ologun Ibrahim Babangida wo̩gi le ibo June 12 o̩dun 1999.
O̩dun ke̩tadinlo̩gbo̩n(27) naa niyi ti awo̩n ijo̩ba ologun igba naa seku pa Abio̩la to jawe olubori ninu ibo naa.
Ibo naa ni o tii yanranti ju lati igba ti a ti n dibo ni Naijiria titi di oni.
Ibi eto ibo naa ni Abio̩la ti na alatako re̩ mo̩le. Eto ibo naa ni ko ti si e̩ni to beere e̩sin tabi e̩ya Abio̩la. Bi o tile̩ je̩ pe igba keji Abio̩la naa tun je̩ e̩le̩sin Musulumi, ko tile̩ si e̩ni to pariwo re̩.
Ni gbogbo igba naa, Abio̩la ni e̩ni to lowo ju ni ile̩ Adulawo. Inu awuyewuye lati gba e̩to̩ Abio̩la pada naa ni awo̩n kan ti lo̩ yinbo̩n pa Kudirat Abio̩la ti o je̩ iyawo keji oloogbe naa.
O̩po̩ ilees̩e̩ Abio̩la ni o ti run nigba ti Ko̩la Abio̩la to je̩ ako̩bi naa gbe̩sb le o̩po̩ dukia ge̩ge̩ bi Olalekan to je̩ o̩mo̩ Kudirat se salaye fun oniroyin SundayVanguard .
O ni baba oun ni ti awo̩n ba fe̩ pin ogun, ki awo̩n se aye̩wo e̩je̩ awo̩n o̩mo̩ naa to ba ba ti oun mu. Olalekan salaye yii pe gbogbo wa la mo̩ pe buje̩ bu danu ni baba oun. O ni ojoojumo̩ ni awo̩n eniyan maa n to si e̩nu o̩na awo̩n fun iranlo̩wo̩ ti baba oun si maa n se e. O ni eyi je̩ ki o̩po̩ maa pe ara wo̩n ni o̩mo̩ Abio̩la.
Olalekan ni eyi lo mu ki awo̩n lo se aye̩wo o̩mo̩ o̩go̩fa (120) nigba ti me̩rindinlaado̩rin (66) je̩ o̩mo̩ ale, me̩rinlelaado̩ta (54) si yege.