NYSC sọ ìdí tó fi kọ̀ láti fún àgùnbánirọ̀ ní ìwé ẹ̀rí

NYSC sọ ìdí tó fi kọ̀ láti fún àgùnbánirọ̀ ní ìwé ẹ̀rí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọn ní ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àlàyé,
Ajọ tó ń rí sí àgùnbánirọ̀ lórílẹ-èdè Nàìjíríà, NYSC ti sàlàyé ìdí tí wọ́n fi kọ̀ láti fún ọ̀kan nínú àgùnbánirọ̀ wọn, Ushie Rita Uguamaye ní ìwé ẹ̀rí pé ó kópa nínú sísin orílè-èdè Nàìjíríà, tí wọ́n sì tún fi oṣù méjì kún àkókò tó yẹ kó fi sin ìlú.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede lọjọ Aiku, NYSC ni, Arabinrin Uguamaye pẹlu nomba idanimọ LA/24B/8325, ẹni ti ọpọ mọ si Raye n koju ijiya pe o kuna lati fara rẹ han fun ayẹwo NYSC ti oṣu Kẹrin ọdun 2025.

NYSC tun wọgile iroyin to ni pe wọn gbe igbesẹ yii nitori ọrọ kobakungbe ti agunbanirọ yii sọ si iṣejọba Aarẹ Bola Tinubu.
“Lati tan imolẹ si iroyin ofege to n lọ kiri pe a ko fun agunbanirọ ni iwe ẹri nitori o sọ ọrọ kobakungbe si ijọba, eyi lo jẹ iro to jina si otitọ ,” atẹjade naa ṣalaye.

“Rita jẹ ọkan lara awọn agunbanirọ 131 ti a kọ lati fun ni iwe ẹri leyin ti wọn sẹ si ofin NYSC. Ni ti ọrọ Rita, a fi oṣu meji kun ọjọ to yẹ ko lo nitori o kuna lati lọ fun ayẹwo NYSC oṣu Kẹrin, eyi to lodi si ofin NYSC.
“O ṣe koko ki a jẹ ki ilu mọ pe eyi kii ṣe pe a gbe igbesẹ nitori iwa to hu ṣaaju .”