Nwafor júbà Ehora nígbà tí ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ ìyàwó rẹ̀
Yínká Àlàbí
Ogbeni Remigus Nwafor ni ọkọ Nneka Roseann Nwafor ti o fẹsẹ fẹẹ nigba ti ọwọ ajọ to n gbogun ti oogun oloro NDLEA (National Drug Law Enforcement Agency) tẹ iyawo rẹ.
Ọwọ tẹ arabinrin yii n isọ rẹ to wa ni Trade Fair Complex ni Ọjọ ti ipinlẹ Eko. Nneka jẹwọ pe oun ati ọkọ oun lawọn jijọ n sisẹ naa. O ni abala ti oun ni oun fẹ lọ fi jisẹ ki ọwọ awọn ajọ naa to tẹ oun. O ni isẹ ọkọ oun ni lati mọ bi oogun oloro naa se maa wọ inu ike itọte ti oun ra nigba ti oun gbọdọ mọ bi egboogi naa se maa de ibi to n lọ.
Ọgọrun un (100) giraamu Cocaine ati ọọdunrun (300) giraamu Phenacetine ni arabinrin dọgbọn gbe si inu ike itọte obinrin. Ilu Malabo ni orileede Equatorial Guinea ni o yẹ ki egboogi naa lọ ti ọwọ awọn agbofinro ko ba tẹẹ.