NLC dúnkokò ìyanṣẹ́lódì tí ìjọba kò bá yọ kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá kan

NLC dúnkokò ìyanṣẹ́lódì tí ìjọba kò bá yọ kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá kan

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó jọ pé fànfà tó wà láàrin ìjọba Orílẹ̀ yìí àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kò tí ì jẹ rodò rárá o bí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Nàìjíríà, Nigeria Labour Congress àti akẹgbẹ́ rẹ̀, Trade Union Congress, TUC ti kéde pé àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́rú ọjọ́ kẹjọ oṣù Kọkànlá ọdún 2023.

Ohun tí wọ́n ń bèèrè fún ni pé kí ìjọba yọ ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo kúrò ní ipò tó wà àti abẹ́ṣinkáwọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ náà tí wọ́n lọ́wọ́ nínú bí wọ́n ṣe fìyà jẹ ààrẹ NLC, Joe Ajaero ní ìpínlẹ̀ náà.

Ìpè yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn kan ṣe ìkọlù sí ààrẹ NLC, Joe Ajaero ní ìpínlẹ̀ Imo lásìkò tí wọ́n ń gbèrò láti ṣe ìwọ́de tako ìjọba ìpínlẹ̀ látàrí gbèsè owó oṣù tí wọ́n jẹ àwọn òṣìṣẹ́..

Igbákejì ààrẹ NLC, Adewale Adeyanju sọ fún àwọn akọ̀ròyìn ní ìlú Abuja ohun tó le yẹ ìyanṣẹ́lódì náà kò sí àyàfi tí ìjọba bá dáhùn gbogbo ìbéèrè àwọn lórí ìyà tí wọ́n fi jẹ Ajaero.

NLC ní ọjọ́ márùn-ún ni àwọn fún ìjọba láti dáhùn ìbéèrè àwọn bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹta oṣù Kọkànlá.

Wọ́n ní bí ìjọba kò bá dáhùn ìbéèrè àwọn dandan ní kí àwọn bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì lọ́jọ́rú.