NLC àti TUC sèwọ́de lórí fífi òfin de ọtí líle inú ọ́rá

NLC àti TUC sèwọ́de lórí fífi òfin de ọtí inú ọ́rá

Yínká Àlàbí

Ajọ awọn osisẹ NLC ati TUC (Nigerian Labour Congress ati Trade Union Congress) pẹlu awọn to n pese ọti inu ọra ṣe iwọde.
Wọn se iwọde lọ si ileesẹ awọn to n ṣe amojuto ounjẹ, oogun ati egboogi NDLEA (National Agency for Food and Drug Administration and Control) to wa ni Eko.
Iwọde naa da lori ki ijọba ma se fofin de oti inu ọra mọ.
Wọn ni ti ijọba ba se eleyii, akoba gidi lo maa jẹ fun awọn to n sisẹ nibẹ ati awọn to n taa.
Pẹlu akọle ti wọn kọ kaakiri kadibọọdu ti wọn gbe dani salaye pe, eniyan bii miliọnu kan ati aabọ lo maa padanu isẹ ti ijọba ba si gunle fifi ofin de naa.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here