Nitori Gomina AbdulRasaq, Muka Ray-Eyiwumi fa awon osere lo si Kwara.

Gomina Abdurazak

Mary Seunfunmi Fagbohun

Awon egbe osere ni Kwara se ipolongo nla kaakiri igboro ilu Ilorin lati kede isejoba eleekeji fun Gomina AbdulRahman AbdulRasaq, lori ise takuntakun ti gomina naa ti se latehin wa.

Gbajumo oserekunrin ni, Muka Ray-Eyiwumi, eni ti o je oluranlowo gomina,  ni o se agbateru ipolongo naa, pelu awon alakoso ijoba ti won si wo ewu akanse ati fila ni bi ogorun won.

Ajo NAN rohin pe imura won n so erongba won si awon olugbe ileto naa nipase orin, ni bi won se n fi  asia ati iwe atejade ti o ni orisirisi akole han bii, Gomina AbdulRasaq leekeji; aropo merin ati merin o je mejo, Muka fun AA, larin awon toku.

Won jade lati agbegbe Igbimo awon onise ona ati asa ti ipinle naa ti o wa ni Geri Alimi Ilorin, koja si popona Ibrahim Taiwo, popona Emir,  popona Post Office-Challenge, ona Ahmadu Bello, titi de ile ijoba nibi ti won ti kase ipolongo na nle.

Agbekale eto yi wa lati owo  igbakeji oluranlowo agba fun Gomina lori asa ati irin ajo afe, Ogbeni Eyiwumi Muka Ray, ogbontarigi  osere Yoruba ati asagbejade ere ti o je omo bibi ijoba ibile Irepodun ni ipinle naa.

Lara awon osere ati alatilehin egbe oselu APC ti won kun ibi ipolongo yii ni, egbe osere ni orile ede Nigeria (ANTP), egbe ere itage ati isipopada aworan ni orile ede Nigeria (TAMPAN) egbe ode ati onise aabo, egbe awon onse fiimu ti orile ede Nigeria, egbe olorin ni orile ede Nigeria ti ipinle Kwara (PMAN).