Nigeria Gb’ewúròó sójú Mali
Yínká Àlàbí
Ikọ agbabọọlu alafọwọgba obinrin ti gbogbo aye mo si D’Tigress ti fagba han ikọ ti Mali ni ilu Abidjan, ni orileede Cote d’Ivoire ni ọjọ isinmi yii pẹlu ami ayo mejidinlọgọrin si mẹrinlelọgọta (78-64) ti ikọ Mali.
Orileede Senegal ni D’Tigress naa ni ipele to gbe wọn de asekagba pẹlu orileede Mali yii.
Arabinrin Ezinne Kalu kan n fọwọ ju bọọlu sawọn alatako ni bi Okoronkwo naa se n foju awọn agbaọọlu Morocco ri ni ọsẹ to kọja.
Igba mejila ọtọọtọ ni awọn ikọ obinrin Nigeria ati Mali ti pade nibi Afrobasket yii. Orileede Nigeria jawe olubori lẹẹmẹjọ nigba ti iko Mali jawe olubori lẹẹmarun un. Ipade akọkọ waye ni ọdun 2003, wọn na Nigeria ni ami ayo mejilelaadọta si mẹrindinlaadọta (52-46). Ipade ẹlẹẹkeji waye ni ọdun 2005, orileede Nigeria na wọn ni ami ayo mọkandinlaadọrin si mẹrinlelogoji (69-44). Ipade kẹta waye ni ọdun 2009, wọn na Nigeria ni ami ayo mọkanlelogoji si mẹtadinlogoji (41-37). Ipade kẹrin waye ni ọdun 2011, wọn na Nigeria ni ami ayo mọkanlelaadọrin si mejilelọgọta (71-62). Ipade karun un waye ni ọdun 2013 ti wọn na Nigeria ni ami ayo mejidinlọgọrin si marundinlaadọta (78-45) ni ibẹrẹ pẹpẹ idije. Igba kẹfa naa waye ni ọdun kan naa, wọn tun na Nigeria ni ami ayo mẹtadinlọgọta si aadọta (57-50).
Ipade keje waye ni ọdun 2017, Nigeria na wọn ni ami ayo mejidinlaadọta si mẹtadinlaadọta (48-47). Ipade kẹjọ waye ni ọdun 2019 nibi ti Nigeria ti na wọn pelu ami ayo mọkandinlọgọrin si mejidinlọgọta (79-58).
Ipade kẹsan an waye ni ọdun 2020, Ikọ Nigeria tun na wọn ni ami ayo mẹrinlelaadọrin si mọkandinlọgọta (74-59). Ipade kẹwaa waye ni ọdun 2021, Nigeria tun na wọn ni ami ayo aadọrin si mọkandinlọgọta.
Ipade kọkanla waye ni ọdun 2022 ni abala FIBa World Cup, Nigeria tun na wọn ni ami ayo mẹtalelaadọrin si mọkandinlaadọrin (73-69).
Igba kejila lo waye ni ọjọ isinmi, ọjọ kẹta osu kẹjọ, ọdun 2025, orileede Nigeria lo tun gbo ewuro si wọn loju pẹlu ami ayo mejidinlọgọrin si mẹrinlelọgọta (78-64). Eyi ni o jẹ igba karun un D’Tigress Nigeria maa gba ife eye naa leralera.
Gbogbo awọn ọmọ Nigeria lo ti n ki awọn iko D’Tigress ku oriire nitori Aarẹ tun maa fi oye dawọn lọla pẹlu ile ati owo rọgunrọgun.