Nígbẹ̀yìn, Iléẹjọ́ gba béèlì Emefiele láàhámọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ó jọ́ pé àdúrà Gómìnà banki ilẹ̀ẹwa nígbàkan rí ,ti gbà báyìí o,bí Adájọ́ Olukayode Adeniyi ti ilé-ẹjọ́ gíga tó ń jòkó nílùú Àbújá ti gba béèlì Gómìnà fún báńkì àpapọ̀ tẹlẹri, Godwin Emefiele.
Adeniyi pa á lásẹ pé kí Emefiele má a tẹlé àwọn agbẹjọrò rẹ̀ lọ lẹsẹkẹsẹ, tí wọ́n sì ṣe ìlérí pé àwọn yóó mu wá sí ilé-ẹjọ́ ní ọsẹ tó ń bọ̀ tàbí ọjọkijọ tí ilé-ẹjọ́ bá fẹ́ kó farahàn
Gẹ́gẹ́ bí Adájọ́ ṣe sọ, Gómìnà Báńkì àpapọ̀ tẹlẹ náà gbọdọ̀ fi gbogbo àwọn ìwé ìrìnà rẹ̀ sílẹ̀ ní ilé-ẹjọ́.
Bákan náà ni Adájọ́ ní òpin gbọdọ̀ dé bá wíwà rẹ̀ ní àhámọ́, pẹ̀lú bí ó ṣe ti wà níbẹ̀ láti bí ọjọ́ mọ́kànlelaadọjọ, tí ìjọba àpapọ̀ àti agbẹjọ́rò àgbà lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà sì gbọdọ̀ tẹ̀lé àṣẹ ilé-ẹjọ́