NDLEA mú Daddy G.O ní ṣọ́ọ̀ṣi Eko, wọ́n ló gbé òògùn olóró wọ Nàìjíríà

NDLEA mú Daddy G.O ní ṣọ́ọ̀ṣi Eko, wọ́n ló gbé òògùn olóró wọ Nàìjíríà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọlọ́run nìkan ló mọ ẹni tó ń ṣe ti Ẹ̀ lọ̀rọ̀ dà báyìí ní bí àjọ tó ń gbógun ti gbígbé oògùn olóró lórílẹ̀-èdè yìí, ”National Drug Law Enforcement Agency” (NDLEA) ti nawọ́ gan olórí ìjọ kan nílùú Èkó, Pasitọ Adefolusho Olasele, fún ẹ̀sùn gbígbé oògùn olóró láti Ghana wọ Nàìjíríà.

”The Turn of Mercy Church” ni wọn pe orukọ ṣọọṣi ti Pasitọ Adefolusho Olasele jẹ oludasilẹ rẹ naa.

Femi Babafemi, Agbẹnusọ NDLEA, lo kede eyi ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹjọ ọdun 2025.

Atẹjade naa ṣalaye, pe Pasitọ Olasele tawọn eeyan tun mọ si Abbas Ajakaiye, ti ko oogun to lodi sofin wọ Naijiria lati Ghana lọpọ igba.

O fi kun un pe o ti to bii oṣu meloo kan ti Oludasilẹ ijọ tọwọ ṣẹṣẹ ba yii ti n sa kiri kọwọ ofin ma ba a tẹ ẹ.

Ọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ ọdun 2025 ni wọn pada mu un ni ṣọọṣi rẹ to wa ni Okun Ajah, lagbegbe Lekki, ipinlẹ Eko.
Nigba to n ṣalaye kikun nipa oogun oloro ti Pasitọ Adefolusho Olasele, n ko wọle ati bi ọwọ ṣe pada tẹ ẹ, Agbẹnusọ NDLEA, Babafemi, sọ pe:
” Lẹyin ọpọ oṣu to ti n sa lọ silẹ okeere kọwọ ma ba a tẹ, Oludasilẹ ijọ The Turn of Mercy Church, Prophet Adefolusho Aanu Olasele (alias Abbas Ajakaiye) ti bọ sọwọ ofin fun kiko oogun oloro to lodi sofin wọ Naijiria.

” Ni ṣọọṣi rẹ to wa ni Okun Ajah, Ojuna Ogombo, Lekki, nipinlẹ Eko ni a ti mu un lọjọ kẹta oṣu Kẹjọ, 2025.

” Awọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA to ti n duro de e lati aarọ pe ko pari isin ọjọ naa kawọn le mu un ni wọn pada mu Adefolusho nirolẹ, bo ṣe n jade lati inu ọgba ile ijọsin rẹ.

“Eemeji lo ti sa lọ si Ghana, lati oṣu Kẹfa ti awọn ọtẹlẹmuyẹ ti n ṣọ ọ, lẹyin ti wọn gba oogun oloro Loud ìṣí meji ti wọn lo ko de lati Ghana.

“Bakan naa ni a tun ri i pe o lọwọ si omiran ti a mọ si cannabis.

” Ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa ọdun 2025 ni a kọkọ gba oogun oloro ti iwọn rẹ to igba kilo (200kg) lọwọ rẹ ni Okun Ajah, nigba ti ọkọ to gbe iwọn ẹẹdẹgbẹrin (700kg) egbogi kan naa tun ha lọjọ kẹfa, oṣu Keje 2025.”

Atẹjade NDLEA sọ pe Pasitọ Adefolusho jẹwọ pe oun n ko egbogi oloro wọ Naijiria lati Ghana, ati pe ori omi ni ọkọ to n gbe e wa maa n gba.

Wọn lo tun jẹwọ pe oun ti sa kuro ni Naijiria lọ si Ghana, lẹyin ti oun bọ mọ ajọ yii lọwọ lẹẹmeji.