Naijiria nílò biliọnu mé̩rin dín díè̩ fún àtúnse afárá Third Mainland Bridge

Naijiria nílò biliọnu mé̩rin dín díè̩ fún àtúnse afárá Third Mainland Bridge

Mary Fágbohùn

Minisita to n ri soro awọn akanṣe iṣẹ ode, David Umahi, ti sọ pe atunṣe afara Third Mainland Bridge ko ni sai na ijọba ni biliọnu mẹrin din diẹ.

Gege bi o se so, awọn opo to gbe afara naa duro labẹ omi ti yinrin tan, nitori naa o nilo atunse.

O so eyi di mimo to n sọrọ nibi ipade igbimọ alaṣẹ Naijiria niluu Abuja, eyi ti Aare Bola Tinubu dari re nile Aare niluu Abuja.

Lona kan naa FEC bowolu bilionu marun din die fun akanse ise meji, 539 bilionu naira fun atunse Carter Bridge niluu Eko ati 134 bilionu naira lati satunse ona Kano-Kastina.

Minisita naa tenumoo pe afara iwọn kilomita mọkanla – oun ti Eko ni awọn agbaṣẹ ṣe sọ pe o ti bajẹ kọja atunṣe, ti ileeṣẹ Julius Berger ti wọn ni ko wo o si sọ pe 359 biliọnu naira ni yoo ṣe afara tuntun.

Bi ose kan seyin ni ijoba apapo fi ofin de awon oko ajagbe nla lati mase rin lori afara Third Mainland ohun.

Eyi si kọ ni igba akọkọ ti wọn ṣe atunṣe afara naa.

Lọdun 2020 si 2021, oṣu bii mẹjọ ni wọn fi ti afara naa fun atunṣe.

Ọdun 1990 ni wọn ṣi Afara Third Mainland Bridge fun lilo, lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn fi kọ ọ ni abẹ iṣejọba ologun Ibrahim Babangida.