Naijiria ko ni obinrin to dara ju lagbaye – Ruger

Naijiria ko ni obinrin to dara ju lagbaye – Ruger

 

Mary Fágbohùn

 

Gbajumo olorin, Michael Adebayo Olayinka, ti a mo si Ruger, ti so pe awon obinrin Naijiria jinna si eyi to dara ju lagbaye.

 

Gege bi o se so, eyikeji okunrin to ba n rin irinajo kaakiri le jeri si okodoro yii.

 

O so eyi ninu iforo-wani-lenu-wo kan to se laipe yii pelu ile ise asoromagbesi The Beat 99.9 FM, Eko.

 

“Mo le so dajudaju pe, a [omo Naijiria] o ni obinrin to dara ju lagbaye. Bee ni, Okodoro ni. Ko si okunrin to le lo kaakiri [agbaye] ti yoo so bee [pe obinrin Naijiria lo dara ju].

 

“A ni awon obinrin to dara sugbon a o ni eyi to dara ju. E ro pe ko si awon obinrin alawo funfun to ni ‘oyan nla’? Won paro fun wa pe awon obinrin oyinbo ko ni oyan nla. Hmm, e nilo lati ri. Mo ti ri,” ni o so.

 

Olorin ‘Asiwaju’ naa so pe oun ko le lailai korin pelu afenifere obinrin lori itage ni Naijiria bi oun se n se ni ile okeere nitori pe “opuro ni awon obinrin Naijiria.”

 

O wi pe, “Ni temi, mi o ro pe mo le ri eyikeyi obinrin lori itage ni Naijiria. Nitori pe pupo ninu awon to n da mi lebi lori bi mo se n jo pelu awon afenifere obinrin lori itage ni igba naa je omo Naijiria. Mi o fe isoro enikeni. Maa lo nigba miran maa si kuro.

 

“Loooto, mi o fe isoro pelu awon omo Naijiria. Awon eniyan mi buru. Ati pe opolopo obinrin ni Naijiria wa ninu ibasepo nitori naa mi o fe ki enikeni fa mi laso. Opuro ni awon obinrin Naijiria.”

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here