N tó fà á t’áwọn ọmọbìnrin fi ń tètè bàlágà lóde òní.
Ìwòye àwọn onímọ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Láti ọdún pípẹ́ báyìí ni ìwádìí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń kọminú lórí bí àyípadà ṣe ń bá bí àwọn ọmọdé ṣe ń tètè bàlágà ní ọjọ́ orí kékeré ju ti bí ó ṣe máa ń wáyé nígbà àwọn ayé babańlá wa lọ.
Ìgbà àti àkókò tí àwọn ọmọbìnrin fi ń rí nǹkan oṣù wọn, tí wọ́n ń bẹ̀rẹ̀ sí ní gún ọyàn tó jẹ́ àpẹẹrẹ ìbàlágà ló ti ń wáyé ní ọjọ́ orí kékeré, tó sì ń yá ju bó ṣe máa ń wáyé lọ.
Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, ìwádìí ní ọjọ́ orí tí àwọn ọmọbìnrin yóò fi máa rí nǹkan oṣù wọn ti dínkù pẹ̀lú ọdún mẹ́rin ju ti ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn lọ.
Ní oṣù Karùn-ún, ìwádìí kan ní àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n bí láàárín ọdún 1950 sí 1969, ọdún méjìlá sí mẹ́tàlá ni àwọn ọmọbìnrin máa ń bẹ̀rẹ̀ nńkan oṣù.
Nígbà tó fi máa di ọdún 1990, ọjọ́ orí tí àwọn ọmọbìnrin fi ń rí nǹkan oṣù ti já wálẹ̀ sí àárín ọdún mọ́kànlá sí méjìlá.
Bó ṣe wá rí káàkiri àgbáyé rèé kódà àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní orílẹ̀ èdè South Korea ti ń kọminú pé àwọn ọmọbìnrin tí ọjọ́ orí wọn kò ju ọdún mẹ́jọ lọ ni àmì ìbàlágà ti ń wà lára wọn nípa bí wọ́n ṣe ń bẹ̀rẹ̀ sí ní gúnyàn tàbí bíbẹ̀rẹ̀ nǹkan oṣù.
Wọ́n ní ipele mẹ́rìndínlógún ni àlékún náà fi wáyé láàárín ọdún 2008 sí 2020.
Ọ̀jọ́gbọ́n kan ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Emory University ní Atlanta, Audrey Gaskins ní bí ọjọ́ orí tí àwọn ọmọbìnrin fi ń tètè bàlágà ṣe ń dínkù yìí ní ìpalára fún ìlera.
Àwon tó ń ṣe ìwádìí yìí bí Gaskins gbàgbọ́, ti wọ́n sì ń kọminú pé bí àwọn omọbìnrin ṣe ń tètè bàlágà ní ìpalára fún àwọn obìnrin náà nígbà tí wọ́n bá dàgbà tán.
Ìwádìí tuntun míì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé bí àwọn ọmọbìnrin ṣe ń tètè bàlágà ń ṣokùnfà ìdí tí ọdún àwọn obìnrin kò fi ń lè bímọ mọ́ láì tíì dàgbà púpọ̀.
Bákan náà ni wọ́n ni ó máa ń fà á tí àwọn obìnrin kìí tètè rí nǹkan oṣù wọn mọ́ nígbà tí ọjọ́ orí wọn kò bá ì tíì dàgbà púpọ̀ àti pé ó jẹ́ ohun tó lè tètè mú ẹ̀mí obìnrin lọ.
Bí àwọn ṣe ń tètè ń bàlágà wà lára àwọn nǹkan tí wọ́n ní ó máa ń fa àwọn àrùn bíi jẹjẹrẹ ọyàn àti ti ilé ọmọ, ará àsanjù, ìtọ̀ ṣúgà àtàwọn àìsàn ọkàn míì.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣì ń ṣèwádìí láti mọ ohun tó ń fa èyí àmọ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì California, Berkeley, Brenda Eskenazi ní ìwádìí fi hàn pé bí ẹ̀yà ara bá ṣe ń pèsè àwọn hòmóònù tó níṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ bíi estrogen fún ìgbà pípẹ́ si ni ó máa ń fa àlékún bí àwọn kòkòrò tó máa ń fa jẹjẹrẹ ṣe máa ń dàgbà sí.
Eskenazi ní ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ni ìwádìí kò ì tíì fojú rẹ̀ hàn lórí bí wọ́n ṣe ń mú àyípadà bá ìgbé ayé èèyàn àti ipa tí Ẹ̀yà ara tó lágbára méjì ló máa ń ṣiṣẹ́ papọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ ìbàlágà lára èèyàn, àwọn náà ni hypothalamic-pituitary-adrenal (HPA) àti hypothalamic-pituitary-gonadal (HPG).
Àwọn ẹ̀yà ara yìí ló máa ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ọpọlọ tó ń jẹ́ hypothalamus, èyí ló máa ń ṣe atọ́ná bí àwọn ẹ̀yà ara yòókù ṣe máa ń ṣiṣẹ́ sí. Ohun ló máa ń jẹ́ kí èèyàn mọ̀ pé ebi ń pa òun tàbí ara gbígbóná.
Gaskins ṣàlàyé pé ní nǹkan bíi ọdún mẹ́wàá sí ogún ọdún sẹ́yìn, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì máa ń rò ó pé ara àsanjù àtàwọn purotéènì tí ọ̀rọ́ “adipokines” máa ń pèsè ló ń ṣokùnfà bí àwọn ọmọbìnrin ṣe ń tètè bàlágà àmọ́ ó ní ìwádìí tuntun ti ní àwọn nǹkan tó ń fà á jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Ó ní àwọn ìwádìí tuntun láti bíi ọdún mẹ́ta báyìí ṣàfihàn pé èémí tí kò dára tí àwọn ọmọdébìnrin ń mí sínú náà ń fa nǹkan wọ̀nyí.
Ọ̀pọ̀ àwọn ìwádìí tuntun yìí ni wọ́n ṣe ní orílẹ̀ èdè South Korea, tí wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Seoul, Busan àti Incheon wà lára àwọn ìlú tí afẹ́fẹ́ wọn kò dára tó ní àgbáyé.
Ìwádìí kan tí ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ewha Womans ní Seoul gbé jáde ní àwọn ṣàwárì ìbáṣepọ̀ láàárín afẹ́fẹ́ tí kò dára tí awọn ọmọdé ń fa sára àti bí wọ́n ṣe ń tètè bàlágà.
Lára àwọn nǹkan tó ń ba atẹ́gùn jẹ́ táwọn èèyàn ń gbà símú ni “sulfur dioxide, nitrogen dioxide, carbon monoxide àti ozone”.
Látara ọkọ̀ àtàwọn iléeṣẹ́ ńláńlá ni àwọn kẹ́míkà yìí fi ń wọ afẹ́fẹ́.
Ní ọdún 2022, ìwádìí kan tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe ní Poland ṣàgbéyẹ̀wò àwọn obìnrin 1,257 tí wọ́n sì ri pé afẹ́fẹ́ gáàsì nitrogen tí wọ́n ń fà símú ló ṣokùnfà ìdí tí wọ́n fi tètè bẹ̀rẹ̀ nǹkan oṣù lẹ́ni ọdún mọ́kànlá.
Gaskins àtàwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ míì ṣàwárí rẹ̀ pé àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n ní àwọn ìlú tí wọ́n ti le máa fa atẹ́gùn tí kò dára sára pàápàá àwọn afẹ́fẹ́ tó ti dàpọ̀ mọ́ àwọn kẹ́míkà bíi PM2.5 ní ó ṣeéṣe kí wọ́n rí nǹkan oṣù wọn ní ọjọ́ orí tó kéré púpọ̀.
Ó ní kẹ́míkà PM2.5 le wọ inú ẹ̀jẹ̀ èèyàn kíákíá, tí èèyàn bá ti fà á símú.
“A ti ṣàwárí PM2.5 nínú ibi ọmọ, ilé ọmọ rí, gbogbo ẹ̀yà ara ló lè wọ̀.”
Ó wòye pé ẹ̀rí tuntun tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé PM2.5 àtàwọn kẹ́míkà míì tó ń wọ ara jẹ́ ọ̀kan péré nínú bí àwọn kẹ́míkà tí kò dára ṣe ń gba àyíká wọ ẹ̀yà ara èèyàn, tí wọ́n sì ń mú àyípadà ńlá bá àgọ́ ara.
Bákan náà ló ní ìpalára tí àyípadà ojú ọjọ́ àtàwọn kẹ́míkà tí wọ́n fi ń ṣe ike ni a kò tíì mọ̀ rárá.
Ó ní ó dàbí pé nǹkan ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni lórí èyí.