Iyaadin Shade Okoya, to je gbajugbaja onise okowo tati iyawo olowo tabua, Alhaji Rsaq Akanni Okoya, ti sọ pe oun ko padanu nnkan kan lori bi oun se fe agbalagba okunrin.
Shade, to je eni ọdun mejidinlaadota bayii ṣe igbeyawo pẹlu Okoya ni 1999 nigba ti olowo tabua naa je eni ọdun marundinlaadorin (65, ti obinrin naa si je eni ọdun mokanlelogun nigba naa.
Amo sa, nigba to n sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba, Shade fowo gbaya pe oun ko padanu ohunkohun rara nitori pe oun ko fẹ ọdọmọkunrin.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìrírí rẹ̀ nínú ìgbéyàwó naa, ó sọ pé inú òun dùn gan-an ni.
Ó ní, “Ọkọ mi jẹ́ ọ̀làwọ́ pẹ̀lú mi. O sì ń gbèjà mi níbikíbi. Ọlọ́run sọ pé ibi tí màá wà nìyí. A pàdé ara wa; ó sì nífẹ̀ẹ́ mi. Kò sì fi àkókò ṣòfò rárá.
“Inu mi dun ninu igbeyawo mi pẹlu rẹ. O dagba ju mi lọ, ṣugbọn mi o ro pe mo padanu ohunkohun nitori pe mi o fẹ ọdọmọkunrin kan.”