Mr Eazi kéde èròńgbà rè̩ láti díje du ipò Ààre̩
Mary Fágbohùn
Olorin Niajiria ati olokowo, Oluwatosin Ajibade, ti a mo si Mr Eazi, ti safihan erongba ojo iwaju re fun ipo Aare.
Olorin ‘Skin Tight’, eni to sese segbeyawo pelu Temi Otedola, omobinrin olowo tabua, Femi Otedola, safihan ero re lati di Aare ninu fonran to fi lede lori Snapchat.
O so di mimo pe oun ti n woye lati dije fun Aare orileede Afrika fun igba die.
“Mo ti n ro o. Mo ro pe o to akoko lati so fun yin. Aare ti ko wa owo ati agbara sugbon to n ronu saaju ohun gbogbo, to je omode, to jafafa, to si le mu orileede yin dara si.
“Nitori naa, mo n kede ara mi bii eni to si sile fun ipo Aare,” o kede bee.
Bo ti le je pe a bi ni Naijiria, Mr Eazi ni ibasepo timotimo pelu Ghana, nibi to ti kekoo nipa orin to si ti bere ise orin re.
Iroyin jade pe Ghana nipa lori eya orin re, eyi ti a n pe ni orin Banku.
Ni bii odun die seyin, pupo ninu awon ilumooka Naijira ti n wo agbo oselu bii eni adiboyan tabi afisipo.
Pupo ninu won si ti so erongba ojo iwaju won fun ipo oselu osere tiata Eniola Badmus, eni to safihan erongba re lati di Sinato loju iwaju ni osu kerin 2025.
Sinato teleri Senator, Ben Bruce, nigba kan ri si pe olorin Davido lojo kan yoo di Gomina ipinle Osun.