Mo ti fẹ́yàwó kejì, mi ò ṣe mọ́- Ọkọ ìyàwó kan

Mo ti fẹ́yàwó kejì, mi ò ṣe mọ́- Ọkọ ìyàwó kan

Fẹ́mi Akínṣọlá

Túláàsì lóhun ó jókòó, ò lóò ráyè.
Iwájú Onídàájọ Abilékọ S.M Akintayọ, tile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan tó wà ní Mapo, nílùú Ìbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni àwọn tọkọ-taya méjì kan, Ọ̀gbẹ́ni Kazeem Jẹjẹ àti Abilekọ Kafilat Jẹjẹ, gbé ara wọn lọ. Kazeem ló gbé ẹjọ́ ìyàwó rẹ̀ lọ sile-ẹjọ ọ̀hún, nǹkan tó sì ń fẹ́ ni kí adájọ́ tú ìgbéyàwó tó wà láàrin àwọn méjèèjì ká.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Kazeem ti sọ pé, ‘‘Oluwa mi, ẹ̀bẹ̀ kan ṣoṣo ti mo bẹ̀ báyìí ni pé kẹ́ ẹ tú ìgbéyàwó ogún ọdún tó wà láàrin èmi àti ìyàwó mi yìí ká, kẹ́ ẹ sì kìlọ̀ fún un pé kò gbọdọ̀ wáá bá mi lẹ́nu iṣẹ́ mi mọ́ láti fa wàhálà pẹ̀lú mi. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti sú mi pátápátá, mi ò ṣe mọ́ , kò sífẹ̀ẹ́ láàrin àwa méjèjì mọ́, ojoojúmọ́, ìjà ni nínú ilé. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ní nǹkan bíi ogun ọdún sẹ́yìn ni mo pàdé rẹ̀, gbogbo ìwà rẹ̀ ló tẹ́ mi lọ́rùn pátá, a ṣètò ìdána, bẹ́ẹ̀ ni mo sanwó orí rẹ̀ fáwọn ẹbí rẹ̀. Kò sóhun tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ mi tí mi ò fún wọn. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ rárá tá a fẹ́ra wa sílé tán tí ìyàwó mi yìí bẹ̀rẹ̀ sí í yọwọ́-kọ́wọ́, wàhálà ni lójoojúmọ́, nígbà tó tún yá ló bá tún ń lọ rojọ mi níta pé mo ti lo nǹkan ọmọkùnrin mi láti fi ṣòògùn owó lòun kò ṣe rí ọmọ bí látìgbà tá a ti ṣègbéyàwó.

‘‘ Kò síbi tí mo lè dé báyìí, ṣe làwọn èèyàn á máa fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, bẹ́ẹ̀ kí í ṣe pé mo lówó lọ́wọ́ ká baà sọ pé lóòótọ́ ni mò lo nǹkan ọmọkùnrin mi fún oògùn owó. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti lọ fẹjọ́ rẹ̀ sun àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ìyàtọ̀ nínú ìṣesí rẹ̀. Bí mo gbé igbá nínú ilé, mi ò mọ̀ ọ́n gbé ni, kò sígbà tí má a jáde kúrò nínú ilé, ṣe nìyàwó mi á máa tú gbogbo ẹrù mi láti wò ó bóyá mo lóògùn kan tí mo fi pamọ́ fún un. Nígbà tó yá ni bàbá ìyàwó mi gbà mí nímọ̀ràn pé kí ń lọ fẹ́yàwó kejì síta. Àmọ̀ràn pàtàkì ọ̀hún ni mo tẹ̀lé tí mo fi lọ fẹ́yàwó mìíràn síta báyìí. Ọlọ́run sì ti ṣe é, ìyàwó ọ̀hún ti bímọ fún mi, èyí tó fihàn gbangba pé irọ nìyàwó mi ń pa mọ́ mi pé mo ti lo nǹkan ọmọkùnrin mi láti fi ṣòògùn owó. Ẹ ṣáà bá mi lé e kúrò nínú ilé mi lohun tí mo ń fẹ́ báyìí ’’.

Níwọ̀n ìgbà tí kò sí olùjẹ́jọ́, ìyẹn Abilékọ Kafilat Jẹjẹ, nílé-ẹjọ́, adájọ́ ilé-ẹjọ́ náà sún ìgbẹ́jọ́ síwájú di ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kìn-ín-ní, ọdún 2024 tó ń bọ̀ yìí.

Bákan náà ló kàn án nípa fáwọn akọ̀wé kóòtù pé kí wọ́n rí i dájú pé wọ́n fún olùjẹ́jú níwèé ìpẹ̀jọ́, kó lè yọjú sílé-ẹjọ́ lọ́jọ́ tí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ máa tún wáyé.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here