Mo sì wà nínú ẹgbẹ́ APC- Lai Mohammed
Yínká Àlàbí
Alhaji Lai Mohammed, Minisita fun eto iroyin àti Àṣà tẹ́lẹ̀, sọ pé òun ṣi jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ olóòtítọ́ ti APC, ṣùgbọ́n kò tún kópa ní gbangba mọ́; ó ń ṣiṣẹ́ lábẹ́nú fun ẹgbẹ́. Ó si salaye ìtìlẹ́yìn rẹ̀ sí ìjọba Ààrẹ Bola Tinubu kò yí padà rárá.
Ó sọ èyí nibi ayeye ikarundinlogun (15th Convocation Lecture) ní Yunifásítì Achievers, Owo, ni ipinle Ondo níbi tí ó ti gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ń parí ẹ̀kọ́ níyànjú láti jẹ́ alágbára.
Ó ṣàlàyé pé ìwé-ẹ̀rí yunifásítì kì í dá aṣeyọrí lójú; ìmótuntun, ìgboyà àti ìfaradà ló ṣe pàtàkì.
Lai Mohammed, ẹni tí ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Minisita fún ọdún mẹ́jọ ní ìjọba Buhari, pe ara rẹ̀ ní alátìlẹ́yìn gidi fún ìjọba Tinubu, ó sì rọ àwọn ará Nàìjíríà láti ṣèrànwọ́ fún Ààrẹ nínú oro ààbò orílẹ̀-èdè, nítorí pé àìlera ààbò ń dí ìdàgbàsókè ọrọ̀-aje dúró. Ó tún rántí bí ìfaradà àti ìfarapa tí ó dojukọ́ ní àkókò ìjọba PDP ṣe mú kí òun di ẹni tí orílẹ̀-èdè mọ̀ lónìí.
Nípa ti Yunifásítì Achievers, àwọn alákóso rẹ̀ sọ pé ilé-ẹ̀kọ́ náà ń tẹnumọ́ ìwa rere, ìmúra ẹ̀kọ́ tó péye àti igboran, tí kò sì gba oogun olóró tàbí egbe okunkun laaye (cultism). Wọ́n fi kún un pé ilé-ẹ̀kọ́ náà kì í ta ìwé-ẹ̀rí, ṣùgbọ́n ń gbé akẹ́kọ̀ọ́ tí ó ní ìwa rere àti ìmúra siṣẹ́ gíga jáde.









