Mo sì ń gbé sàdáńkátà fún orin Davido ‘Unavailable’ – Logos Olori [FONRAN]
Mary Fágbohùn
Olorin Naijiria to n dide bo, Logos Olori ti salaye pe oun si n gbade fun kiko orin Davido ti mi igboro titi ‘Unavailable’ sile.
O so eyi nigba to n soro lori ibasepo re pelu Davido.
Ninu ijomitoro oro re lori mohunmaworan Hiptv, Logos Olori eni to fi idi re mule pe oun lo ko orin Davido to lo jakejado ‘Unavailable’ sile, o tun salaye pe Peruzzi ati Davido se awon atunto kan ninu re lati le e ba ara won mu.
Nigba to n soro lori igbade fun, Logos Olori wi pe Davido si n san owo fun n.
“Ni ti ayipada ati atunto oro orin. Peruzzi wa, o si ko ese orin kan to dara gidi. E mo pe mo wa pelu eya temi, mo si n so itan ara mi sugbon David fe itan tire. Nitori naa ayipada atunto oro orin waye, sugbon ohun to da le lori ko yipada.
“Bee ni won si n gbade fun mi. E mo pe gbogbo nnkan nipa Davido je mimoose ise.