Mo setán láti kú’ – Tems

Mo setán láti kú’ – Tems

Mary Fágbohùn

Olorin Naijiria olugbafe eye Grammy, Temilade Openiyi, ti a mo si Tems, ti safihan pe oun setan lati doju ko saare nigba ti oun fi eya orin takasufe ti gbogbo eniyan mo kaakiri orile ede sile fun R&B.

Tems wi pe oun ni igbagbo pupo ninu ara oun to bee ti oun ko bikita bi oun o ba “je nnkankan tabi da enikeni” pelu R&B.

Olorin ‘Essence’ naa so pe oun kan fe ki “ifiranse naa jade sita ni.”

O safihan eyi ninu ijiroro re pelu asoro orin kiakia Amerika, Kendrick Lamar, ninu iwe irohin iforo-wani-lenu-wo Interview Magazine to gbe jade laipe yii.

Tems wi pe, “Mo setan lati ku. Mo ni igbagbo pupo ninu ara mi to fi je pe mi o bikita nipa pe mo le ma je nnkankan tabi enikeni. Mo kan fe fi ifiranse kan sita. Mo kan fe ki igbohunsafefe mi maa jade. Mo ro pe, ‘Koda bi eniyan mewaa ba gbo je, o dara.’ Sugbon nigba to ya, mo n gbo orin Naijiria sugbon mi o kun fun emi to—mo feran Celine Dion, nitori naa, mo feran iru imolara bee, mo setan lati fo sile lati idagẹẹrẹ-okegiga. Bayii ni mo se fe ki orin mi ri ni gbogbo igba, orin takasufe ko si fun mi ni iru nnkan bayii.”

O wi pe gbogbo eniyan ti oun beere fun imoran lowo won nigba naa, ro oun lati se orin takasufe, wi pe, “Ona kan ti o fi le se eyi ni orin takasufe. Kii se pe orin re ko dara, o kan je pe ko ye fun Naijiria. Awon omo Naijiria ko feran iru re.”

Olorin ti a fa sile fun ife eye Oscar so pe oun ko lati jowo re nitori pe owo kii se ilepa oun. O fikun un pe nnkan ti oun fe ni “lile igbohunsafefe.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here