Mo sèpinnu láti wá’lé sí Abuja – Banky W
Mary Fágbohùn
Olorin ati oloselu Naijiria, Bankole Wellington, ti a mo si Banky W, ti soro leyin to fidi remi ninu eto idibo, o wi pe, oun sepinnu lati wa ile si Abuja.
Leyin eto idibo ojo karun-din-ni-ogbon osu keji, oludije fun ipo omole igbimo asoju fun agbegbe Eti-Osa ninu egbe oselu People’s Democratic Party padanu ipo naa sowo alatako re, Thaddeus Attah ti egbe oselu Labour Party.
Nigba to fi fonran kan lede ni ojo Aje ni oju opo Instagram re, Banky W safihan ohun to pinnu lati se leyin ti o padanu ninu eto idibo naa.
O wi pe, “Eyi lo ye ko je isin idupe wa. Leyin ti eto idibo ti pari, a wa, a n sajoyo, a n dupe lowo Olorun. Ati pe maa so oro kekere pe e wa wo ohun ti Olorun se.
“Leyin naa a lo iyen lati ru igbagbo wa soke a si dupe lowo Olorun. Leyin eyi ni a pari isin ti mo si lo si Abuja lati wa ile ati aaye fun ofiisi.”