Mo rí àwọn géńdé ọkùnrin tí wọ́n ń sùn lórí ìdúró  – Small Doctor 

Mo rí àwọn géńdé ọkùnrin tí wọ́n ń sùn lórí ìdúró  – Small Doctor

Mary Fágbohùn

Olórin Afrobeats, Small Doctor, ti fi ìdàníyàn to jinlẹ̀ hàn lórí ipa ìlòkulò oògùn lórí àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà.

Olorin to dagba ni ilu Agege naa ranti abewo to se laipe si adugbo ọmọde rẹ, eyi ti o jẹ ki iyalẹnu baa. O sọ pe lakoko ibẹwo naa oun rii diẹ ninu awọn ọdọ langba ti o dagba ti won n sun lori iduro nitori asilo oogun.

O sọ pe iriri naa dun oun lo jẹ ki oun maa rawo ẹbẹ fun igbogun ti ilokulo oogun.

Olórin náà rántí bí ogbontarigi ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Wasiu Ayinde ṣe gba òun nímọ̀ràn ní ọdún mẹ́fà sẹ́yìn pé ki oun dá ilé iṣẹ́ àtúnṣe sílẹ̀, ó sọ pé iṣẹ́ tó ń mówó wọlé ni lọ́jọ́ iwájú.

Lori X rẹ, Small Doctor kowe, “Okunrin kan wa to n kọrin lodi si asilo oògùn lori ayelujara, o ti se die ti mo ti ri fonran re (David nnkankan ti mi o ranti daadaa) mo ro pe a nilo rẹ ni akoko yi.

“Mo rin kiri ni adugbo ni ọjọ Aiku ati pe ohun ti mo rii jẹ ibanujẹ pupọ.

“Wasiu Ayinde so fun mi ni odun mefa seyin lati da ile-ise atunse sile, o so pe epo tuntun ni, okunrin naa ri ojo iwaju.

“Ibanujẹ pupọ julọ ni nigba ti mo de adugbo mi, mo rii diẹ ninu awọn odo langba ti a dagba papọ ti wọn sun lọ lori iduro, diẹ ninu won paapaa n ṣe awọn ipo aṣiwere diẹ nigba ti wọn n sun.

“Ibanuje gidi.”