Mo pàdánù àkó̩bí mi nítorí owó – Ibrahim Chatta
Mary Fágbohùn
Gbajugbaja oṣere tiata, Ibrahim Chatta ti ṣalaye bi o ṣe padanu ọmọ rẹ to kọkọ bi si ile iwosan kan ni ipinlẹ Eko nitori ko ri owo itọju san.
Chatta, so oro yi lasiko to n sọrọ ninu fọnran kan to jade lori ayelujara.
O ṣalaye pe oun sa gbogbo agbara oun lati wa owo fun itọju ọmọ to di oloogbe naa ṣugbọn pabo lo ja si.
O ni kireeti pako ẹlẹrindodo ni oun fi sin ọmọ ọhun lọdun naa.
“Malik kọ ni akọbi mi. Ọmọ obinrin ni akọbi mi. Mo padanu ọmọ naa nitori mi o ri owo ile iwosan san.
“A gbe lọ si ile iwosan ni agbegbe Iddo ni ipinlẹ Eko. Mo fẹ sẹ rin lati Ijora Badia lọ si Makoko, ti mi o si ri owo titi ọmọ naa fi jade laye. Kireti Coca-Cola ni a fi sin ọmọ naa.”
Chatta ni oun ko ki n fi bẹ sọrọ ọmọ rẹ oloogbe, to si jẹ pe aipẹ yii gan an ni oun sọ ọrọ naa fun awọn mọlẹbi oun lẹyin ti oun de lati irinajo lọ si orilẹede Qatar.
“Ọjọ ti mo lọ si Dubai, ti mo si ra ẹbun nla wa fun ọmọ mi obinrin kankan soso ti mo bi, Hawawu, ni iya rẹ bẹrẹ si ni ma binu pe mi o ra ẹbun fun oun.
“Mo sọ fun un lọjọ naa pe mo ti bi ọmọ obinrin kan ri, ti mo si ṣalaye bi o ṣe jade laye. Gbogbo wọn bẹrẹ si ni ma sunkun nitori wọn ko gbọ nipa itan yii ri lati ẹnu mi.”
Gbajumọ osere tiata ni Ibrahim Tapa, ọmọ ilu Bacita nipinlẹ Kogi nii se, ẹya Tapa Lempe si lo jẹ.
Ọjọ Ketala osu Kẹwaa ọdun 1970 ni won bi gbajumọ osere naa, to je ọdun mejilelaadọta sẹyin.
Amọ Chatta ti pẹ nilẹ Yoruba, to si n ba wọn kopa ninu ere Yoruba lorisirisi.
Lara awọn gbajumọ ere ti Chatta ti kopa ni Wehinwo, Alaaaru, Police and Thief, Akirisore, Agboorun ati bẹẹ bẹẹ lọ.