Mò ń bọ̀ wá bá yín jẹ àkàrà ojú pópó tí ẹ n dín torí mi – Makinde

Mò ń bọ̀ wá bá yín jẹ àkàrà ojú pópó tí ẹ n dín torí mi – Makinde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Sé àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ẹní tó láyà ló lè
gbé ilé ńlá.,Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti ní òun máa jíròrò pẹ̀lú àwọn olùgbé agbègbè Ologuneru ní pilú Ibadan èyí tí àkànṣe iṣẹ́ òpópónà Circular Road ṣe ìdíwọ́ fún ibùgbé wọn.

Makinde ní gẹ́gẹ́ bí ìlérí òun láti ri pé gbogbo èèyàn ìpínlẹ̀ Oyo ló jẹ mùnkúndùn ìjọba àwaarawa, ó ní òun máa ṣe àbẹ̀wò sí òpópónà náà, bá aráàlú sọ̀rọ̀, tí òun yóò sì ri dájú pé gbogbo àwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ sí owó gbà mábinú ni àwọn máa fún.

Bákan náà ló ní àwọn máa wòye sí pípèsè ààyè míì fáwọn tí òpópónà náà ṣe àkóbá fún ibùgbé wọn.

Gómìnà Makinde ló sọ èyí lásìkò tó gbé àbá ìsúná ọdún 2026 síwájú ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Kọkànlá, 2025.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here