Mo gba AKA ní ìmò̩ràn pé kó ra ìbo̩n láti fi dáàbò bo ara rè̩ – Burna Boys
Mary Fágbohùn
Olorin Afrobeats, Damini Ogulu, ti a mo si Burna Boy, ti so edun okan re lori iku ojiji to pa olorin South Africa, Kiernan Forbes ti a mo si AKA.
Ogulu lo si oju opo Instagram re lati se afihan orin ti ko se agbejade re nibi to ti korin nipa iku olorin naa.
Gegebi o se so, o ti gba AKA ni imoran ri pe ko ra ibon leyin ti oloogbe naa pe ni ‘ehanna’ nitori pe o ni ikan.
“Kinni gbogbo eleyi da le lori? Mo sese gbo pe o ku, mo ri fonran naa nile ounje. O ka mi laya/O mu mi pada ronu igba atijo ti o ri mi pelu ibon ti o si pe mi ni ehanna/Leyin naa mo so fun e pe ki iwo naa ni ikan,” lo se ko orin naa.
Olorin ‘Last Last’ naa tun toka si ilara to ni si olorin naa, o wi pe bo tile je pe iwa won yato sita, oun o fe ki o ku.
“Sugbon mi o fe ko ku, bee lori pelu emi ati iwo, mo nikan pelu, kii se pe omokunrin naa o ki n ku loo sugbon mo ro pe o mo ni/ Ati pe mi o ba o ni ija kankan/
“Ika! Mo nireti pe ki won mu awon to se ika yi/ Mo nireti pe ki o sun n re, bo ti le je pe a o re/ Leyin gbogbo ojo a o dagba naa ni,” o tesiwaju.
Lati igba laasigbo to waye ni odun 2019, ti awon omo orile-ede South Africa n pa awon omo orile Naijiria ati awon omo Afrika miiran, ni Burna Boy ti bu enu ate lu iru iwa bee to si dunkoko pe oun o ni de orile-ede naa mo.
Amo sa, oro naa tun di pupo si laarin oun ati olorin South Africa ni ori Twitter.
Ninu atejade kan ti won ti pare bayii, Burna Boy dunkoko mo AKA ti o si so fun n pe ki o sona abo to nipon.
“Nigba miiran, ti mo ba ri e, o je lo wa abo to nipon, ni iboji Gambo, wa a nilo re,” ni ohun to ko sibe.
Olorin South African naa ni won yinbon pa ninu ikolu kan ti waye ni ile ounje Durban, South Africa. Ore re tipetipe, Hip Tee Bello‘Tibz’ Motsoane, ni won seku pa pelu ninu akolu naa.