Mo fẹ́ dupò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun lọ́dún 2026- Omisore

Mo fẹ́ dupò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun lọ́dún 2026- Omisore

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àgbà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, Sénétọ̀ Iyiola Omisore, ti kéde èròngbà rẹ̀ láti dupò gómiìnà ìpínlẹ̀ Osun ní odún 2026 lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún.

Omisore, ẹni to fi gba kan jẹ igbakeji gomina, kede eyi loju opo X rẹ lọjọ Ṣatide, to si ni oun yoo jẹ ki ikede oun di mimọ ni ọfiisi ẹgbẹ oṣelu APC lọjọ Isẹgun, ọjọ Keje, oṣu kẹwaa ọdun 2025.

Omisore sọ loju opo X rẹ pe “ẹyin eeyan mi nipinlẹ Osun, lẹyin ọpọ ijiroro ati ifọrọwanilẹnu wo, mo ti pinnu lati kede erongba mi lati jade dupo Gomina ipinlẹ Osun ni ọdun 2025 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu wa, APC.”
O fikun ọrọ rẹ pe ipolongo ibo oun yoo da lori dida ireti awọn eeyan pada, mimu atunṣe ba iṣejọba ati pipese ọjọ ọla rere fun awọn eeyan nipinlẹ naa.

Omisore ni ”ẹyi ki n ṣe iṣẹ mi nikan, ajọsepọ wa ni, mo n pe iyin pe ki ẹ wa fọwo sowọ pọ pẹlu mi lati gbe ipinlẹ Osun siwaju.”
Omisore dupo gomina ni ọdun 2014 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ko to di pe o darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Igbagbọ wa pe o wa lara awọn oludije to ṣee ṣe ki wọn gba tikẹẹti lati soju ẹgbẹ APC ninu eto idibo to n bọ.

Omisore, jẹ igbakeji gomina laaarin ọdun 1999 si 2003 labẹ ẹgbẹ oṣelu Alliance for Democracy (AD), to si tun di sẹnetọ to soju ipinlẹ Osun laaarin 2003 si 2011.

Sẹnẹtọ Omisore fidirẹmi ninu ibo gomina lọdun 2014, nigba ti Rauf Aregbesola wọle eto idibo naa.

Bakan naa lo tun ti wa ninu ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party (SDP) nigba kan ri.

Omisore tun dupo gomina lọdun 2018, ko to di pe o darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ọdun 2021.

Lara awọn ipo ti Omisore ti dimu ri ipo akọwe agba ẹgbẹ oṣelu APC.