Mo darapọ mọ́ ẹgbẹ́ ADC tó ń fẹ́ mi, fẹ́ bùkátà mi – Gbadebo Rhode-Vivour
Yínká Àlàbí
Oludije du ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu Labour ni ọdun 2023 sugbon ti kadara ko see loore ni igba naa ti digba dagbọn lọ si ẹgbẹ oselu ADC (African Democratic Congress). O ni o dara ki eniyan lọ si ẹgbẹ to ba n fẹ ni to si tun n fẹ bukata ẹni.
Ẹgbẹ oselu ADC ni awọn agba ẹgbẹ kaakiri ti n darapọ mọ lati le sẹgun ẹgbẹ oselu APC ti ijọba wa lọwọ wọn. Ẹgbẹ ADC ni awọn fe gba ọmọ Naijiria kuro ninu isẹ ati osi to n ba wọn ja.
Ilu Eko ni agbegbe ijọba ibilẹ Alimoso ni Gbadebo Rhode-Vivour ti n fi idunnu rẹ han pe “ Inu mi dun lati darapọ mọ ẹgbẹ oselu ADC lasiko ti orileede yii nilo rẹ. Adura mi si Ọlọrun ni ki awọn olori ati ẹgbẹ oselu darapọ lati le ri ọna abayọ si isoro orileede yii.”
“Ẹgbẹ alatako yii nikan lo le yọ Naijiria kuro ninu ọfin. Mo ti salaye yii ni kete ti ibo ọdun 2023 pari pe ẹgbẹ oselu alatako ko le fọnka ki wọn jawe olubori afi ki gbogbo wa fọwọ sowọ pọ lati le se aseyori ninu eto idibo to n bọ lọdun 2027.”
Ọrọ awọn ọlọpaa orileede yii ko tilẹ fẹ ye mi mọ nitori iru ọwọ ti wọn yọ ni ọjọ Ẹti tiii se alẹ Satide ti ọga oun darapọ mọ ẹgbẹ oselu ADC. Ọgbẹni Olalekan Anjolaiya to n sisẹ pọ pẹlu Gbadebọ lo salaye yii, o ni bi o tilẹ jẹ pe awọn ti fi to awọn ọlọpaa leti nipa ipade ọjọ naa. O ni iyalẹnu nla lo tun jẹ fun awọn nigba ti awọn ọlọpaa ko jẹ ki awọn lo gbọngan to yẹ ki awọn lo, o ni awọn ni lati di igba di agbọn lọ si ibomiran ni ijọba ibilẹ naa.
Ọgbeni George Ashiru to jẹ olori ẹgbẹ oselu ADC ni apẹẹrẹ ijawe olubori ni didarapọ ti Gbadebo darapọ mọ ẹgbẹ awọn. O ni eyi maa jẹ ki o soro fun ẹgbẹ oselu APC lati fẹyin awọn balẹ l’ọdun 2027.
Ara awọn to tun sọrọ nibi ipade naa ni Ọjọgbọn Ola Olateju to jẹ asoju Igbakeji Aarẹ tẹlẹ ri ni orileede yii, Atiku Abubakar. O ni ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ ni igbagbọ ninu ara wọn pe ko si ipo ti awọn ko lee di mu ninu ẹgbẹ ADC.
O tun salaye siwaju sii bayii pe “ ki awọn ọmọ ẹgbẹ ma se bẹru ki wọn ma se sojo pe awọn ko le gba Naijiria silẹ lọwọ ọda ti wọn wa bayii. Ẹgbẹ ADC ni a ba maa pe ni ẹgbẹ ibi ko ju ibi. Kii se ẹgbẹ ẹlẹyamẹya tabi ẹlẹsinmẹsin. A ti kọja ẹgbẹ oselu lasan, a kora jọ lati gba Naijiria kalẹ lọwọ awọn amunisin ni.”