Mide Martins sè’rántí màmá rẹ 

Mide Martins sè’rántí màmá rẹ

Mary Fágbohùn

Oṣere Mide Martins ti ṣe alabapin igboriyin kan lori Instagram lati sami si ayẹyẹ ọdun ketalelogun iku iya rẹ, Funmi Martins.

Nigba to n se aṣaro lori ipadanu ti o si wa ninu iranti rẹ, Martins ṣapejuwe iya rẹ ti o ku bi okuta iyebiye ti o ṣọwọn ati Angẹli otitọ ni irisi eniyan.

Mide ṣafihan ibanujẹ nla, o ṣe tokasi pe ironu nipa iya rẹ tẹsiwaju lati mu omije jade loju re, nigba ti o n tẹnu mọo pe awọn iranti nipa iya oun ti o nifẹẹ si ati ipa ayeraye ko le parẹ.

Ó ní: “Ọdún mẹ́tàlélógún sẹ́yìn, bíi àná! Oluwafunmilayo Florence Anike mama mi. Ó ti pé ọdún mẹ́tàlélógún láti ìgbà tí mo ti pàdánù ìyá mi àyànfẹ́ ati ọ̀rẹ́ àtàtà! Angẹli gidi kan ninu awọ ara eniyan. Mi o le ṣalaye bi o ṣe saferi rẹ to ninu ọrọ, Maami. Mo si n ronu nipa rẹ lọpọlọpọ, ati ni gbogbo igba ni mo n ri ara mi ti n ta omije silẹ. Awọn iranti ẹlẹwa ati iyebiye rẹ ko se e gbagbe, ati pe ipa rẹ lori agbaye yii kii yoo parẹ. Tẹ siwaju lati ma a sinmi ni alaafia ni itanna ti ẹlẹda rẹ, Aniike. Mo nifẹẹ rẹ titi aye, Iya mi onin’ure”..