Mi ò tíì rí ìfé̩ òtító̩ láyé mi – Tiwa Savage

Mi o tii ri ifẹ otitọ laye mi – Tiwa Savage

Mary Fagbohun

Olorin Naijiria, Tiwa Savage, ti safihan pe oun ko ti ni iriri ife ni eni odun merinlelogoji.

Olorin naa salaye pe yato si omo oun, Jamil, oun ko ti ni iriri Ife lati odo enikeni.

O ni pelu awon ibasepo ti oun ti ni lateyin wa, oun ri mo pe gbogbo re da lori oro enu lasan ni kii se ife otito.

“Mi o ro pe mo ti ni iriri ife yato si omo mi. Nitori nigba ti mo weyin wo awon ibasepo ti mo ti ni ri, rara, Ife ko niyi. Okan mi kan da si odo enikan ni. Nigba naa mo ro pe mo wa ninu ife. Mi o ro pe mo ni iriri ife otito koda ninu igbeyawo mi,” olorin naa so ninu iforowero pelu with Zeze Mills.

Savage ni oun ti wa gba pe boya oro ife kii se tire nitori opo igba loun ti gbiyanju lera lera lati ri ife sugbon pabo lo ja si.

“Boya ife kii se temi nitori mo ti gbiyanju lopo igba boya kii se ni aye yi,” o fikun un.

E ranti pe Tiwa Savage ati oko re teleri Tunji Balogun, ti a mo si Teebillz, se igbeyawo ni odun 2013 sugbon ti won ko ara won sile ni 2018 bi igbiyanju lati mu ki ibamu wa ninu igbeyawo won ko se seese.

Igbeyawo won ni Olorun bukun pelu omo kan, Jamil.