“Mi ò níi ló̩kàn láti se ìgbéyàwó”- Chike
Mary Fágbohùn
Olorin Naijiria, Chike ti safihan pe oun ko gbero lati se igbeyawo, o pe e ni “igbese̩ omugo̩”.
Ninu iforo-wani-lenu-wo pelu Chude Jideonwo, o ni, “Lero temi, mo ro pe o je igbese̩ omugo̩ lati se igbeyawo. Ero mi niyi”, o so bee.
Olorin “Running” naa ni igbeyawo kii se fun oun.
Chike tun safikun oro re pe idunnu oun da lori ki owo to to owo wa lapo oun.
“Mo nilo opolopo owo ki inu mi le dun,” Chike so bee, o ni kii se ojukokoro sugbon iru aye ti o n fe ni.