Mi ò ní fi ààyè gba èébú ara – Alákóso Tems
Muyiwa Awoniyi, oluṣakoso awọn irawo olorin Naijiria, Tems, Omah Lay (Stanley), ati Lekan, ti ṣe ikilọ nla fun awọn alariwisi, ti o sọ pe oun ko ni gba eyikeyi iwa aibọwọ fun awọn olorin rẹ.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi lede lori X, Awoniyi sọ pe nigba ti yoo foju fo o ti won ba pẹgan rẹ, ikọlu yowu si Tems, Omah Lay, tabi Lekan won yoo ri pipon oju oun.
“Mo ti sọ tẹlẹ ati pe mo n tun un sọ lẹẹkan sii. O n pẹgan mi? O temilorun. Ṣugbọn ti o ba pẹgan Temi, Stanley tabi Lekan? A o ni iṣoro. ‘Titi di igba miiran, o dabo na ” gege bi o se salaye.
Alaye rẹ tẹle oro eebu ara ti enikan so si Tems laipẹ ti o soro ti ko yẹ leralera nipa ara rẹ, ni pataki awọn idi rẹ.