Mi ò je̩ e̩niké̩ni ní àlàyé ìdí tí ìgbéyàwó mi fi kùnà – Bolanle Ninalowo

Mi ò je̩ e̩niké̩ni ní àlàyé ìdí tí ìgbéyàwó mi fi kùnà – Bolanle Ninalowo

Mary Fágbohùn

Osere tiata Naijiria Bolanle Ninalowo ti so pe oun ko je enikeni ni alaye lori idi ti igbeyawo re se kuna.

Irohin jade pe osere tiata naa ni ojo Eti, ninu atejade kan to fi lede ni oju opo Instagram re, kede ipinya to waye laarin oun ati iyawo re, Bunmi.

“Emi ati iyawo mi ti pinnu lati pinya lati lo ona igbeyawo ti o tuka laisi atunse,” ni o so.

Leyin ikede re, fonran iforo-wani-lenu-wo osere tiata naa atijo kan pelu Jideonwo jade si ori ayelujara.

Ninu fonran naa, o soro nipa atunse ti o la koja lati doola igbeyawo re ti o kuna ati lati gba iyawo re pada leyin opolopo igbe aye aisooto re.

Fonran naa lo tun ru ina si aheso oro nipa ohun to se okunfa ipinya won.

Nigba ti yoo fesi si aheso oro naa lori itan Instagram re, osere tiata naa wi pe: “Eni to segun kii soro. Mi o je enikeni ni alaye lori ipinnu aye mi. Awon onirohin ayelujara je alagabagebe to n pongbe fun awo.

“Eyikeyi iforo-wani-lenu-wo to ba n lo kaakiri je ti odun mefa saaju ki n to ri igbeyawo mi eyi to ti dopin bayii. Emi ni mo n sajoyo, eyin le n se iyonu. Olorun to ran mi lowo yoo ran yin lowo.”