Mi ò gbàgbọ́ nínú ìgbéyàwó – Lil Kesh

Mi ò gbàgbọ́ nínú ìgbéyàwó – Lil Kesh

Mary Fagbohun

Akọrin Naijiria, Lil Kesh, ti sọ ero rẹ lori igbeyawo.

Olorin ‘Shoki’ naa fi han pe oun ko gbagbọ ninu igbeyawo, nitori pe ko ṣiṣẹ.

Kesh, ẹni ti o fi han pe oun ti ko ni ololufe fun igba pipẹ, tun ṣafihan pe ko ni ipinnu lati ṣe igbeyawo laipẹ.

Nigba ti o n soro lori eto Esther Show laipe, akọrin naa sọ pe, “Lọwọlọwọ yii, oun ko ni ololufe, eyi si ti wa fun igba pipẹ. Mo pinya pẹlu ọrẹbinrin mi nitori mo rii pe mo le ṣe ohun to dara julọ funrara mi, bii iṣẹ-ṣiṣe mi, ohun gbogbo ti o jẹ pataki si mi ni akoko naa nilo ifiyesi. Ati lati igba naa, mi o ni anfani lati rii ara mi ni aaye kan nibi ti mo ti n ṣe mejeeji papo.

“Yoo jẹ ohun ti o dara lati wa ẹnikan ti yoo jẹ ki n yese. Ṣugbọn bayii, mi o le fi gbogbo ara mi sinu ibaṣepọ nitori pe ti mo ba fẹ ọ, mo gbodo wa aaye fun ọ. Pẹlupẹlu, Mi o kii ṣe ọmọde mọ. Omo odun mokanlelogbon ni mi. Ohun to dara ni pe awọn obi mi ko fi agbara mu mi lati ṣe igbeyawo. Wọn ti gba f’Ọlọrun pe mo yatọ.

“Igbeyawo? Boya, to ba ya. Ṣugbọn fun bayii, mi o ni lokan. Mi o tun ni moomo ṣe ipinnu lati so ẹnikẹni di iya ọmọ fun mi. Bee ni mi o tun ni fi enikeni se ‘iyawo’ laipe yi. Kii se pe mi o fẹ ṣe igbeyawo nitori pe mo fẹ lati ni ominira tabi jẹ ọmọdekunrin, mi o kan gbagbọ ninu igbeyawo. Wọn ko ṣiṣẹ. Se o ti rii oṣuwọn ikọsilẹ? Mo ti rii ọpọlọpọ awọn igbeyawo ti ko ni idunnu. Eyi ko tumọ si pe ko si awon to ni idunnu. Ṣugbọn ni temi, mo fẹ ile alayo ati pe mi o lero pe mo le ṣe eyi bayii. Mi o ni ba ayo elomiran je nitori mo gbodo se igbeyawo.”